1 Angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ sì tún dé, ó sì jí mi, bí ọkùnrin tí a jí lójú oorun rẹ̀, 2 ó sì wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ rí?”
4 Mo sì dáhùn mo sì wí fún angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀, pé, “Kín ni wọ̀nyí, olúwa mi?”
5 Angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí?”
6 Ó sì dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Èyí ni ọ̀rọ̀
7 “Ta ni ìwọ, ìwọ òkè ńlá? Ìwọ yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀ níwájú Serubbabeli: òun yóò sì fi ariwo mú òkúta téńté orí rẹ̀ wá, yóò máa kígbe wí pé, ‘Ọlọ́run bùkún fun! Ọlọ́run bùkún fun!’ ”
8 Ọ̀rọ̀
10 [~2~]“Ṣùgbọ́n ta ni ha kẹ́gàn ọjọ́ ohun kékeré? Nítorí wọn ó yọ̀ nígbà ti wọ́n bá rí okùn ìwọ̀n nì lọ́wọ́ Serubbabeli.
11 Mo sì béèrè, mo sì sọ fún un pé, “Kí ni àwọn igi olifi méjì wọ̀nyí jásí, tí ó wà ní apá ọ̀tún fìtílà àti ní apá òsì rẹ̀?”
12 Mo sì tún dáhùn, mo sì sọ fún un pé, “Kí ni àwọn ẹ̀ka méjì igi olifi wọ̀nyí jásí, tí ń tú òróró wúrà jáde nínú ara wọn láti ẹnu ọ̀pá oníhò wúrà méjì.”
13 Ó sì dáhùn, ó wí fún mi pé, “Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí?”
14 Ó sì wí pé, “Àwọn méjì wọ̀nyí ni àwọn tí a fi òróró yàn, tí ó dúró ti Olúwa gbogbo ayé.”
<- Sekariah 3Sekariah 5 ->