Saamu 79
Saamu ti Asafu.
1 Ọlọ́run, àwọn orílẹ̀-èdè ti wá ilẹ̀ ìní rẹ;
wọ́n ti ba tẹmpili mímọ́ rẹ jẹ́,
wọn di Jerusalẹmu kù sí òkìtì àlàpà.
2 Wọn ti fi ara òkú àwọn ìránṣẹ́ rẹ
fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ní oúnjẹ,
ẹran-ara àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ fún ẹranko ilẹ̀.
3 Wọ́n tu ẹ̀jẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí omi
yí Jerusalẹmu ká,
kò sì ṣí àwọn tí yóò sìn wọ́n.
4 Àwa di ohun ẹ̀gàn sí àwọn tí ó yí wa ká,
àbùkù àti ìfiṣe ẹlẹ́yà sí àwọn tí ó yí wa ká.
5 Nígbà wo, Olúwa ? Ní ìwọ ó máa bínú títí láé?
Yóò ti pẹ́ tó ti owú rẹ yóò ha jò bí iná?
6 Tú ìbínú rẹ jáde sí orílẹ̀-èdè
tí kò ní ìmọ̀ rẹ,
lórí àwọn ìjọba
tí kò pe orúkọ rẹ;
7 nítorí wọ́n ti run Jakọbu
wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ di ahoro.
8 Má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wa sí wa lọ́rùn
jẹ́ kí àánú rẹ wá kánkán láti bá wa,
nítorí tí a rẹ̀ wá sílẹ̀ gidigidi.
9 Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọ́run Olùgbàlà wa,
fún ògo orúkọ rẹ;
gbà wá kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì
nítorí orúkọ rẹ.
10 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa wí pé,
“Níbo ni Ọlọ́run wọn wà?”
Ní ojú wa, kí a mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
kí ó sì gbẹ̀san àwọn ẹ̀jẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ tí a tú jáde.
11 Jẹ́ kí ìmí ẹ̀dùn oǹdè náà wá síwájú rẹ,
gẹ́gẹ́ bí títóbi agbára rẹ
ìwọ ṣe ìtọ́jú àwọn ti a dá lẹ́bi ikú.
12 San án padà sí àyà àwọn aládùúgbò wa nígbà méje
nípa ẹ̀gàn tí wọn ti gàn ọ́ Olúwa .
13 Nígbà náà àwa ènìyàn rẹ,
àti àgùntàn pápá rẹ,
yóò fi ọpẹ́ fún ọ títí láé;
láti ìran dé ìran