ÌWÉ KARÙN-ÚN
107
Saamu 107–150
1 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa , nítorí tí ó ṣeun;
nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.
2 Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà Olúwa kí ó wí báyìí,
àwọn ẹni tí ó rà padà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá,
3 àwọn tí ó kójọ láti ilẹ̀ wọ̀n-ọn-nì,
láti ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn,
láti àríwá àti Òkun wá.
4 Wọ́n ń rìn káàkiri ní aginjù ní ibi tí ọ̀nà kò sí,
wọn kò rí ọ̀nà lọ sí ìlú níbi tí
wọn ó máa gbé.
5 Ebi ń pa wọn, òǹgbẹ gbẹ wọ́n,
ó sì rẹ ọkàn wọn nínú wọn.
6 Ní ìgbà náà, wọ́n kígbe sókè
sí Olúwa nínú ìdààmú wọn,
ó sì yọ wọ́n kúrò nínú ìrora wọn
7 Ó fi ọ̀nà títọ́ hàn wọ́n sí ìlú
tí wọn lè máa gbé.
8 Ẹ jẹ́ kí wọn máa yin Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́
ìyanu rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn,
9 nítorí tí ó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn lọ́run
ó sì fi ìre fún ọkàn tí ebi ń pa.
10 Ọ̀pọ̀ jókòó nínú òkùnkùn àti òjìji ikú,
a dè wọ́n ní ìrora àti ní irin,
11 nítorí tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀
Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ìbáwí Ọ̀gá-ògo,
12 Ó sì fi ìkorò rẹ àyà wọn sílẹ̀;
wọn ṣubú, kò sì ṣí ẹni tí
yóò ràn wọ́n lọ́wọ́.
13 Ní ìgbà náà wọ́n ké pe
ó sì gbà wọ́n nínú ìṣòro wọn
14 Ó mú wọn jáde kúrò nínú
òkùnkùn àti òjìji ikú,
ó sì fa irin tí wọ́n fi dè wọ́n já.
15 Ẹ jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún Olúwa ! Nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sí ọmọ ènìyàn.
16 Nítorí tí ó já ìlẹ̀kùn idẹ wọ̀n-ọn-nì
ó sì ké irin wọn ní agbede-méjì.
17 Ọ̀pọ̀ di aṣiwèrè nítorí ìrékọjá wọn
wọ́n sì pọ́n wọn lójú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
18 Wọ́n kọ gbogbo oúnjẹ
wọ́n sì súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ikú.
19 Nígbà náà wọ́n kígbe sí Olúwa nínú ìṣòro wọn,
ó sì yọ wọ́n nínú ìdààmú wọn.
20 Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀, ara wọn sì dá
ó sì yọ wọ́n nínú isà òkú.
21 Ẹ jẹ́ kí wọ́n fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn.
22 Jẹ́ kí wọn rú ẹbọ ọpẹ́
kí wọn kí ó fi ayọ̀ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ̀.
23 Àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí Òkun nínú ọkọ̀ ojú omi,
wọ́n jẹ́ oníṣòwò nínú omi ńlá.
24 Wọ́n rí iṣẹ́ Olúwa ,
àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ nínú ibú.
25 Nítorí tí ó pàṣẹ, ó sì mú ìjì fẹ́
tí ó gbé ríru rẹ̀ sókè.
26 Wọ́n gòkè lọ sí ọ̀run wọ́n sì
tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibú:
nítorí ìpọ́njú, ọkàn wọn di omi.
27 Wọ́n ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n bí ọ̀mùtí ènìyàn:
ọgbọ́n wọn sì dé òpin.
28 Nígbà náà wọ́n ń kígbe sókè
sí Olúwa nínú ìdààmú wọn,
ó sì mú wọn jáde nínú ìṣòro wọn.
29 Ó sọ ìjì di ìdákẹ́rọ́rọ́
bẹ́ẹ̀ ni ríru omi rẹ̀ dúró jẹ́ẹ́.
30 Inú wọn dùn nígbà tí ara wọn balẹ̀,
ó mú wọn lọ sí ibi tí ọkàn wọn lọ.
31 Jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún
àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn.
32 Jẹ́ kí wọn gbé e ga ní àárín àwọn ènìyàn
kí wọn kí ó sì yìn ín ní ìjọ àwọn àgbàgbà.
33 Ó sọ odò di aginjù,
àti orísun omi di ilẹ̀ gbígbẹ.
34 Ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀
nítorí ìwà búburú àwọn tí ó wà nínú rẹ̀.
35 O sọ aginjù di adágún omi àti
ilẹ̀ gbígbẹ di orísun omi,
36 níbẹ̀ ó mú ẹni tí ebi ń pa wà,
wọ́n sì pilẹ̀ ibi tí wọn ó máa gbé.
37 Wọn fún irúgbìn, wọ́n sì gbin ọgbà àjàrà
tí yóò máa so èso tí ó dára;
38 Ó bùkún wọn, wọ́n sì pọ̀ sí i ní iye
kò sí jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọn kí ó dínkù.
39 Nígbà náà, ọjọ́ wọn kúrú,
ìnira, ìpọ́njú àti ìṣòro wọn sì dínkù,
40 ẹni tí ó da ẹ̀gàn lu ọmọ-aládé
ó sì mú wọn rìn níbi tí ọ̀nà kò sí.
41 Ṣùgbọ́n ó gbé aláìní sókè kúrò nínú ìnira
ó mú ìdílé wọn pọ̀ bí agbo ẹran.
42 Àwọn tí ó dúró sì rí i, inú wọn sì dùn
ṣùgbọ́n gbogbo olùṣe búburú yóò pa ẹnu rẹ̀ mọ́.
43 Ẹni tí ó bá gbọ́n, jẹ́ kí ó kíyèsi nǹkan wọ̀nyí