1 Balaamu wí fún Balaki pé, “Kọ́ pẹpẹ méje fún mi níbí, kí o sì mú akọ màlúù méje àti àgbò méje wá fún mi.” 2 Balaki ṣe bí Balaamu ti sọ, àwọn méjèèjì fi akọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti àgbò kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.
3 Nígbà náà Balaamu sọ fún Balaki pé, “Dúró ti ẹbọ sísun rẹ kí èmi sì lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan. Bóyá
4 Ọlọ́run sì pàdé rẹ̀, Balaamu sì sọ pé, “Mo tí ṣe pẹpẹ méje, lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan mo ti fi akọ màlúù àti àgbò kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ.”
5
6 Ó sì padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì ba tí ó dúró ti ẹbọ sísun rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìjòyè Moabu. 7 Nígbà náà ni Balaamu sọ ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ jáde wí pé,
11 Balaki sọ fún Balaamu pé, “Kí lo ṣe fún mi? Mo gbé ọ wá láti fi àwọn ọ̀tá mi bú, ṣùgbọ́n o kò ṣe nǹkan kan, ṣùgbọ́n o bùkún wọn!”
12 Ó sì dáhùn wí pé, “Ṣé kí n má sọ nǹkan tí
13 Nígbà náà Balaki sọ fún un pé, “Wá pẹ̀lú mi sí ibòmíràn tí o ti lè rí wọn; wà á rí díẹ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn. Láti ibẹ̀, wá fi wọ́n bú fún mi.” 14 Ó sì lọ sí pápá Sofimu ní orí òkè Pisga, ó sì kọ́ pẹpẹ méje síbẹ̀ ó sì fi akọ màlúù àti àgbò kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.
15 Balaamu ṣo fún Balaki pé, “Dúró níbí ti ẹbọ sísun rẹ nígbà tí mo bá lọ pàdé rẹ̀ níbẹ̀.”
16
17 Nígbà náà ó lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì bá à tí ó dúró ti ẹbọ sísun rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè Moabu. Balaki sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni
18 Nígbà náà ó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ sísọ,
25 Nígbà náà ni Balaki wí fún Balaamu pé, “O kò kúkú fi wọ́n bú, bẹ́ẹ̀ ni o kò súre fún wọn rárá!”
26 Balaamu dáhùn ó sì wí fún Balaki pé, “Ǹjẹ́ èmi kò ha ti wí fún ọ pé, gbogbo èyí tí
27 Nígbà náà Balaki sọ fún Balaamu pé, “Wá jẹ́ kí èmi kí ó mú ọ lọ sí ibòmíràn bóyá yóò tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn kí ó fi wọ́n bú láti ibẹ̀ lọ.” 28 Balaki gbé Balaamu wá sí orí òkè Peori, tí ó kọjú sí aginjù.
29 Balaamu sì wí fún Balaki pé, “Mọ pẹpẹ méje fún mi níbí kí o sì pèsè akọ màlúù àti àgbò fún mi.” 30 Balaki sì ṣe bí Balaamu ti sọ fún un, ó sì gbé akọ màlúù kan àti àgbò lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.
<- Numeri 22Numeri 24 ->