1 [a]Bí wọ́n ti súnmọ́ Betfage àti Betani ní ẹ̀yìn odi ìlú Jerusalẹmu, wọ́n dé orí òkè olifi. Jesu rán méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ síwájú. 2 Ó pàṣẹ fún wọn pé,
4 [~2~]Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà lọ bí ó ti rán wọn. Wọ́n rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà tí a so ní ẹnu-ọ̀nà lóde ní ìta gbangba, wọ́n sì tú u. 5 Bí wọ́n ti ń tú u, díẹ̀ nínú àwọn tí ó dúró níbẹ̀ bi wọ́n léèrè pé, “Ki ni ẹyin n ṣe, tí ẹ̀yin fi ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ n nì?” 6 Wọ́n sì wí fún wọn gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ní kí wọ́n sọ, wọ́n sì jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́ lọ. 7 [~3~]Wọ́n fa ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà tọ Jesu wá. Wọ́n tẹ́ aṣọ wọn sí ẹ̀yìn rẹ̀, òun sì jókòó lórí rẹ̀. 8 Àwọn púpọ̀ tẹ́ aṣọ wọn sí ọ̀nà. Àwọn mìíràn ṣẹ́ ẹ̀ka igi, wọ́n sì fọ́n wọn sí ọ̀nà. 9 [~4~]Àti àwọn tí ń lọ níwájú, àti àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn, gbogbo wọn sì ń kígbe wí pé,
11 [~5~]Jesu wọ Jerusalẹmu ó sì lọ sí inú tẹmpili. Ó wo ohun gbogbo yíká fínní fínní. Ó sì kúrò níbẹ̀, nítorí pé ilẹ̀ ti ṣú. Ó padà lọ sí Betani pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá.
12 [~6~]Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti kúrò ní Betani, ebi ń pa Jesu. 13 Ó rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lọ́ọ̀ọ́kán tí ewé kún orí rẹ̀. Nígbà náà, ó lọ sí ìdí rẹ̀ láti wò ó bóyá ó léso tàbí kò léso. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ewé lásán ni ó rí, kò rí èso lórí rẹ̀. Nítorí pé àkókò náà kì í ṣe àkókò tí igi ọ̀pọ̀tọ́ máa ń so. 14 Lẹ́yìn náà, Jesu pàṣẹ fún igi náà pé,
15 [~7~]Nígbà ti wọ́n padà sí Jerusalẹmu, ó wọ inú tẹmpili. Ó bẹ̀rẹ̀ sí nílé àwọn oníṣòwò àti àwọn oníbàárà wọn síta. Ó ti tábìlì àwọn tí ń pààrọ̀ owó nínú tẹmpili ṣubú. Bákan náà ni ó ti ìjókòó àwọn tí ń ta ẹyẹlé lulẹ̀. 16 Kò sì gba ẹnikẹ́ni láààyè láti gbé ẹrù ọjà títà gba inú tẹmpili wọlé. 17 [~8~]Gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ wọn, ó wí pé,
18 Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin gbọ́ ohun tí ó ti ṣe, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ń gbà èrò bí wọn yóò ti ṣe pa á. Wọ́n bẹ̀rù rògbòdìyàn tí yóò bẹ́ sílẹ̀, nítorí tí àwọn ènìyàn ní ìgbóná ọkàn sí ẹ̀kọ́ rẹ̀.
19 [~9~]Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, bí ìṣe wọn, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde kúrò ní ìlú Jerusalẹmu.
20 [~10~]Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti ń kọjá lọ, wọ́n rí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí Jesu fi bú. Wọ́n rí i pé ó ti gbẹ tigbòǹgbò tigbòǹgbò. 21 Peteru rántí pé Jesu ti bá igi náà wí. Nígbà náà ni ó sọ fún Jesu pé, “Rabbi, wò ó! Igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ìwọ fi bú ti gbẹ!”
22 Jesu sì dáhùn pé,
27 [~14~]Lẹ́yìn èyí, wọ́n tún padà sí Jerusalẹmu.
29 Jesu dá wọn lóhùn pé,
31 Wọ́n bá ara wọn jíròrò pé, “Bí a bá wí pé, ‘Láti ọ̀run wá ni,’ òun ó wí pé, ‘Nígbà tí ẹ mọ̀ bẹ́ẹ̀, èéṣe tí ẹ kò fi gbà à gbọ́?’ 32 Ṣùgbọ́n bí a bá wí pé, àti ọ̀dọ̀ ènìyàn, wọ́n bẹ̀rù àwọn ènìyàn, nítorí pé gbogbo ènìyàn ló gbàgbọ́ pé wòlíì gidi ni Johanu.”
33 Nítorí náà, wọ́n kọjú sí Jesu wọn sì dáhùn pé, “Àwa kò mọ̀.”
11:1 Mt 21.1-9; Lk 19.29-38.
11:4 Mk 14.16.
11:7 Jh 12.12-15.
11:9 Sm 118.26; Mt 21.15; 23.39.
11:11 Mt 21.10-11,17.
11:12 Mt 21.18-19; Lk 13.6-9.
11:15 Mt 21.12-16; Lk 19.45-48; Jh 2.13-16.
11:17 Isa 56.7; Jr 7.11.
11:19 Lk 21.37.
11:20 Mt 21.20-22; Mt 17.20; Lk 17.6.
11:24 Jh 14.13-14; 16.23; Mt 7.7-11.
11:25 Mt 6.14-15; 18.35.
~13~ Àwọn àkọsílẹ̀ àtijọ́ ìwé Marku kan se àfikún ọ̀rọ̀ yìí yín. 26 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá kọ̀ láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn jì wọ́n, baba yín kò ní í dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.11:27 Mt 21.23-27; Lk 20.1-8; Jh 2.18.