1 [a][~2~]Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà, Jesu mú Peteru, Jakọbu àti Johanu arákùnrin rẹ̀, ó mú wọn lọ sí orí òkè gíga kan tí ó dádúró. 2 Níbẹ̀ ara rẹ̀ yí padà níwájú wọn. Ojú rẹ̀ sì ràn bí oòrùn, aṣọ rẹ̀ sì funfun bí ìmọ́lẹ̀. 3 Lójijì, Mose àti Elijah fi ara hàn, wọ́n sì ń bá Jesu sọ̀rọ̀.
4 Peteru sọ fún Jesu pé, “Olúwa, jẹ́ kí a kúkú máa gbé níhìn-ín yìí. Bí ìwọ bá fẹ́, èmi yóò pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mose, àti ọ̀kan fún Elijah.”
5 [~3~]Bí Peteru ti sọ̀rọ̀ tán, àwọsánmọ̀ dídán síji bò wọ́n, láti inú rẹ̀ ohùn kan wí pé, “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹni ti inú mi dùn sí gidigidi. Ẹ máa gbọ́ tirẹ̀!”
6 Bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti gbọ́ èyí, wọ́n dojúbolẹ̀. Ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi. 7 Ṣùgbọ́n Jesu sì tọ̀ wọ́n wá. Ó fi ọwọ́ kàn wọ́n, ó wí pé,
9 [~4~]Bí wọ́n sì ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Jesu pàṣẹ fún wọn pé,
10 [~5~]Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ́ pé, “Kí ni ó fà á tí àwọn olùkọ́ òfin fi ń wí pé, Elijah ní láti kọ́ padà wá?”
11 Jesu sì dáhùn pé,
14 [~6~]Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ ìjọ ènìyàn, ọkùnrin kan tọ̀ Jesu wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó wí pé, 15 “Olúwa, ṣàánú fún ọmọ mi, nítorí tí ó ní wárápá. Ó sì ń joró gidigidi, nígbà púpọ̀ ni ó máa ń ṣubú sínú iná tàbí sínú omi. 16 Mo sì ti mú un tọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ, ṣùgbọ́n wọn kò lè wò ó sàn.”
17 Jesu sì dáhùn wí pé,
19 [~7~]Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi Jesu níkọ̀kọ̀ pé, “Èéṣe tí àwa kò lè lé ẹ̀mí èṣù náà jáde?”
20 [~8~]Jesu sọ fún wọn pé,
22 [~10~]Nígbà tí wọ́n sì ti wà ní Galili, Jesu sọ fún wọn pé,
24 [~11~]Nígbà tí Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì dé Kapernaumu, àwọn agbowó òde tí ń gba owó idẹ méjì tó jẹ́ owó tẹmpili tọ Peteru wá wọ́n sì bí i pé, “Ǹjẹ́ olùkọ́ yín ń san owó tẹmpili?”
25 [~12~]Peteru sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ó ń san.”
26 Peteru dáhùn pé, “Lọ́wọ́ àwọn àlejò ni.”
17:1 Mk 9.2-10; Lk 9.28-36; 2Pt 1.17-18.
17:1 Mt 26.37; Mk 5.37; 13.3.
17:5 Mt 3.17; 12.18; Isa 42.1; Sm 2.7.
17:9 Mt 8.4; 16.20; Mk 3.12; 5.43; 7.36.
17:10 Mk 9.11-13; Mt 11.14; Ml 4.5.
17:14 Mk 9.14-27; Lk 9.37-43.
17:19 Mk 9.28-29.
17:20 Lk 17.6; Mt 21.21; Mk 11.22-23; 1Kọ 13.2; Mk 9.23.
~9~ Àwọn àkọsílẹ̀ àtijọ́ kan se àfikún ọ̀rọ̀ yìí fún yín. 21 Ṣùgbọ́n irú ẹ̀mí èṣù yìí kò ní lọ, bí kò ṣe nípa ààwẹ̀ àti àdúrà.17:22 Mk 9.30-32; Lk 9.43-45; Mt 16.21; 20.17-19; 26.2.
17:24 Ek 30.13; 38.26.
17:25 Ro 13.7; Mt 22.17-21.