1 [~1~]Ó sì pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá jọ, ó sì fún wọn ní agbára àti àṣẹ lórí àwọn ẹ̀mí èṣù gbogbo, àti láti wo ààrùn sàn. 2 Ó sì rán wọn lọ wàásù ìjọba Ọlọ́run, àti láti mú àwọn ọlọkùnrùn láradá. 3 Ó sì wí fún wọn pé,
7 [~3~]Herodu tetrarki gbọ́ nǹkan gbogbo èyí tí a ṣe láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá: ó sì dààmú, nítorí tí àwọn ẹlòmíràn ń wí pé, Johanu ni ó jíǹde kúrò nínú òkú, 8 Àwọn ẹlòmíràn sì wí pé Elijah ni ó farahàn; àwọn ẹlòmíràn sì wí pé, ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́ ni ó jíǹde. 9 [~4~]Herodu sì wí pé, “Johanu ni mo ti bẹ́ lórí, ṣùgbọ́n ta ni èyí tí èmi ń gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí sí?” Ó sì ń fẹ́ láti rí i.
10 [~5~]Nígbà tí àwọn aposteli sì padà dé, wọ́n ròyìn ohun gbogbo fún un tí wọ́n ti ṣe. Ó sì mú wọn, lọ sí apá kan níbi tí a ń pè ní Betisaida. 11 [~6~]Nígbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn sì mọ̀, wọ́n tẹ̀lé e: ó sì gbà wọ́n, ó sì sọ̀rọ̀ ìjọba Ọlọ́run fún wọn; àwọn tí ó fẹ́ ìmúláradá, ni ó sì mú láradá.
12 Nígbà tí ọjọ́ bẹ̀rẹ̀ sí rọlẹ̀, àwọn méjìlá wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Tú ìjọ ènìyàn ká, kí wọn lè lọ sí ìletò àti sí ìlú yíká, kí wọn lè wò, àti kí wọn lè wá oúnjẹ: nítorí ijù ni àwa sá wà níhìn-ín.”
13 [~7~]Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé,
18 [~9~][~10~]Ó sì ṣe, nígbà tí ó ku òun nìkan ó gbàdúrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀: ó sì bi wọ́n pé,
19 [~11~]Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi; ṣùgbọ́n ẹlòmíràn ní Elijah ni, àti àwọn ẹlòmíràn wí pé, ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́ ni ó jíǹde.”
20 Ó sì bi wọ́n pé,
21 Ó sì kìlọ̀ fún wọn, pé, kí wọn má ṣe sọ èyí fún ẹnìkan. 22 [~12~]Ó sì wí pé,
23 [~13~]Ó sì wí fún gbogbo wọn pé,
27 [~16~]
28 [~17~][~18~]Ó sì ṣe bí ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́jọ lẹ́yìn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mú Peteru àti Johanu àti Jakọbu, ó gun orí òkè lọ láti lọ gbàdúrà. 29 Bí ó sì ti ń gbàdúrà, àwọ̀ ojú rẹ̀ yípadà, aṣọ rẹ̀ sì funfun gbòò, 30 [~19~]Sì kíyèsi i, àwọn ọkùnrin méjì, Mose àti Elijah, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀, 31 tí wọ́n fi ara hàn nínú ògo, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ ikú rẹ̀, tí òun yóò ṣe parí ní Jerusalẹmu. 32 [~20~]Ṣùgbọ́n ojú Peteru àti ti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ wúwo fún oorun. Nígbà tí wọ́n sì tají, wọ́n rí ògo rẹ̀, àti ti àwọn ọkùnrin méjèèjì tí ó bá a dúró. 33 [~21~]Ó sì ṣe, nígbà tí wọ́n lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, Peteru wí fún Jesu pé, “Olùkọ́, ó dára fún wa kí a máa gbé ìhín yìí, jẹ́ kí àwa pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fún ìwọ, àti ọ̀kan fún Mose, àti ọ̀kan fún Elijah.” (Kò mọ èyí tí òun ń wí.)
34 Bí ó ti ń sọ báyìí, ìkùùkuu kan wá, ó síji bò wọ́n: ẹ̀rù sì bà wọ́n nígbà tí wọ́n ń wọ inú ìkùùkuu lọ. 35 [~22~]Ohùn kan sì ti inú ìkùùkuu wá wí pé, “Èyí yìí ni àyànfẹ́ ọmọ mi: ẹ máa gbọ́ tirẹ̀.” 36 [~23~]Nígbà tí ohùn náà sì dákẹ́, Jesu nìkan ṣoṣo ni a rí. Wọ́n sì pa á mọ́, wọn kò sì sọ ohunkóhun tí wọ́n rí fún ẹnikẹ́ni ní ọjọ́ wọ̀nyí.
37 [~24~]Ó sì ṣe, ní ọjọ́ kejì, nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti orí òkè, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn wá pàdé rẹ̀. 38 Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan nínú ìjọ ènìyàn kígbe sókè pé, “Olùkọ́ mo bẹ̀ ọ́, wo ọmọ mi: nítorí ọmọ mi kan ṣoṣo náà ni. 39 Sì kíyèsi i, ẹ̀mí èṣù a máa mú un, a sì máa kígbe lójijì; a sì máa nà án tàntàn títí yóò fi yọ ìfófó lẹ́nu, a máa pa á lára, kì í tilẹ̀ ń fẹ́ fi í sílẹ̀ lọ. 40 Mo sì bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ láti lé e jáde: wọn kò sì lè ṣe é.”
41 Jesu sì dáhùn pé,
42 Bí ó sì ti ń bọ̀, ẹ̀mí èṣù náà gbé e ṣánlẹ̀, ó sì nà án tàntàn. Jesu sì bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí, ó sì mú ọmọ náà láradá, ó sì fà á lé baba rẹ̀ lọ́wọ́. 43 [~25~]Ẹnu sì ya gbogbo wọn sí iṣẹ́ títóbi Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nígbà tí hà sì ń ṣe gbogbo wọn sí ohun gbogbo tí Jesu ṣe, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, 44
46 [~26~]Iyàn kan sì dìde láàrín wọn, ní ti ẹni tí yóò ṣe olórí nínú wọn. 47 Nígbà tí Jesu sì mọ èrò ọkàn wọn, ó mú ọmọdé kan, ó gbé e jókòó lọ́dọ̀ rẹ̀. 48 [~27~]Ó sì wí fún wọn pé,
49 [~28~][~29~]Johanu sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́, àwa rí ẹnìkan ó ń fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde; àwa sì dá a lẹ́kun, nítorí tí kò bá wa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”
50 Jesu sì wí fún un, pé,
51 [~30~]Nígbà tí ọjọ́ àti gbà á sókè ń súnmọ́, ó pinnu láti lọ sí Jerusalẹmu. 52 [~31~]Ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ lọ sí iwájú rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sì lọ wọ́n wọ ìletò kan tí í ṣe ti ará Samaria láti pèsè sílẹ̀ dè é. 53 Wọn kò sì gbà á, nítorí pé ó ń lọ sí Jerusalẹmu. 54 [~32~]Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ Jakọbu àti Johanu sì rí i, wọ́n ní, “Olúwa wa, jẹ́ kí a pe iná láti ọ̀run wá, kí a sì pa wọ́n run, bí Elijah ti ṣe?” 55 Ṣùgbọ́n Jesu yípadà, ó sì bá wọn wí. 56 Lẹ́yìn náà Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì lọ sí ìletò mìíràn.
57 [~33~]Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ọkùnrin kan wí fún un pé, “Olúwa, Èmi ń fẹ́ láti máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”
58 Jesu sì wí fún un pé,
59 Ó sì wí fún ẹlòmíràn pé,
60 Jesu sì wí fún un pé,
61 [~34~]Ẹlòmíràn sì wí fún un pé, “Olúwa, èmi yóò tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ṣùgbọ́n jẹ́ kí n kọ́kọ́ lọ dágbére fún àwọn ará ilé mi.”
62 Jesu sì wí fún un pé,
9:1 Mt 10.1,5,7-11,14; Mk 6.7-12; Lk 10.4-11.
9:5 Ap 13.51.
9:7 Mt 14.1-2; Mk 6.14-16; Lk 9.19.
9:9 Lk 23.8.
9:10 Mk 6.30-31; Lk 10.17; Jh 1.44.
9:11 Mt 14.13-21; Mk 6.32-44; Jh 6.1-14; Mk 8.4-10.
9:13 2Ọb 4.42-44.
9:16 Lk 22.19; 24.30-31; Ap 2.42; 20.11; 27.35.
9:18 Mt 16.13-20; Mk 8.27-30; Jh 1.49; 11.27; 6.66-69.
9:18 Lk 3.21; 5.16; 6.12; 9.28; 11.1.
9:19 Lk 9.9; Mk 9.11-13.
9:22 Mt 16.21; Mk 8.31; Lk 9.43-45; 18.31-34; 17.5.
9:23 Mt 16.24-28; Mk 8.34–9.1.
9:24 Mt 10.38-39; Lk 14.27; 17.33; Jh 12.25.
9:26 Mt 10.33; Lk 12.9; 1Jh 2.28.
9:27 Lk 22.18; Mt 10.23; 1Tẹ 4.15-18; Jh 21.22.
9:28 Mt 17.1-8; Mk 9.2-8; 2Pt 1.17-18.
9:28 Lk 8.51; 3.21; 5.16; 6.12; 9.18; 11.1.
9:30 Ap 1.9-11.
9:32 Jh 1.14.
9:33 Lk 5.5; 8.24,45; 9.49; 17.13.
9:35 Lk 3.22; Jh 12.28-30.
9:36 Mt 17.9; Mk 9.9-10.
9:37 Mt 17.14-18; Mk 9.14-27.
9:43 Mt 17.22-23; Mk 9.30-32; Lk 9.22; 18.31-34; 17.25.
9:46 Mt 18.1-5; Mk 9.33-37.
9:48 Lk 10.16; Mt 10.40.
9:49 Mk 9.38-40; Lk 11.23.
9:49 Lk 5.5; 8.24,45; 9.33; 17.13.
9:51 Mk 10.1; Lk 17.11; Jh 4.40-42.
9:52 Mt 10.5; Jh 4.4.
9:54 Mk 3.17; 2Ọb 1.9-16.
9:57 Mt 8.19-22.
9:61 1Ọb 19.20; Fp 3.13.