1 [~1~]Jesu sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó padà ti Jordani wá, a sì ti ọwọ́ Ẹ̀mí darí rẹ̀ sí ijù, 2 [~2~]Ogójì ọjọ́ ni a fi dán an wò lọ́wọ́ èṣù. Kò sì jẹ ohunkóhun ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì: nígbà tí wọ́n sì parí, lẹ́yìn náà ni ebi wá ń pa á.
3 Èṣù sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ fún òkúta yìí kí ó di àkàrà.”
4 [~3~]Jesu sì dáhùn, ó wí fún un pé,
5 Lójúkan náà, èṣù sì mú un lọ sí orí òkè gíga, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ ọba ayé hàn án. 6 [~4~]Èṣù sì wí fún un pé, “Ìwọ ni èmi ó fi gbogbo agbára yìí àti ògo wọn fún: nítorí á sá ti fi fún mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wù mí, èmi a fi í fún. 7 Ǹjẹ́ bí ìwọ bá foríbalẹ̀ fún mi, gbogbo rẹ̀ ni yóò jẹ́ tìrẹ.”
8 [~5~]Jesu sì dáhùn ó sì wí fún un pé,
9 Èṣù sì mú un lọ sí Jerusalẹmu, ó sì gbé e lé ibi ṣóńṣó tẹmpili, ó sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ láti ibí yìí. 10 [~6~]A sá ti kọ̀wé rẹ̀ pé,
12 [~7~]Jesu sì dáhùn ó wí fún un pé,
13 [~8~]Nígbà tí èṣù sì parí ìdánwò náà gbogbo, ó fi í sílẹ̀ lọ fun sá à kan.
14 [~9~]Jesu sì fi agbára Ẹ̀mí padà wá sí Galili, òkìkí rẹ̀ sì kàn kálẹ̀ ní gbogbo agbègbè tí ó yí i ká. 15 [~10~]Ó sì ń kọ́ni nínú Sinagọgu wọn; a ń yìn ín lógo láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ènìyàn wá.
16 [~11~]Ó sì wá sí Nasareti, níbi tí a gbé ti tọ́ ọ dàgbà: bí ìṣe rẹ̀ ti rí, ó sì wọ inú Sinagọgu lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ó sì dìde láti kàwé. 17 A sì fi ìwé wòlíì Isaiah fún un. Nígbà tí ó sì ṣí ìwé náà, ó rí ibi tí a gbé kọ ọ́ pé:
20 Ó sì pa ìwé náà dé, ó fi í fún ìránṣẹ́, ó sì jókòó. Gbogbo àwọn tí ó ń bẹ nínú Sinagọgu sì tẹjúmọ́ ọn. 21 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wí fún wọn pé,
22 [~12~]Gbogbo wọn sì jẹ́rìí rẹ̀, háà sì ṣe wọ́n sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ń jáde ní ẹnu rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Ọmọ Josẹfu kọ́ yìí?”
23 [~13~]Jesu sì wí fún wọn pé,
24 [~14~]Ó sì wí pé,
28 Nígbà tí gbogbo àwọn tí ó wà nínú Sinagọgu gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, inú bi wọ́n gidigidi, 29 [~17~]wọ́n sì dìde, wọ́n tì í sóde sí ẹ̀yìn ìlú, wọ́n sì fà á lọ sí bèbè òkè níbi tí wọ́n gbé tẹ ìlú wọn dó, kí wọn bá à lè sọ sílẹ̀ ní ògèdèǹgbé. 30 [~18~]Ṣùgbọ́n ó kọjá láàrín wọn, ó bá tirẹ̀ lọ.
31 [~19~]Ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Kapernaumu, ìlú kan ní Galili, ó sì ń kọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi. 32 [~20~]Ẹnu sì yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀: nítorí tàṣẹtàṣẹ ni ọ̀rọ̀ rẹ̀.
33 Ọkùnrin kan sì wà nínú Sinagọgu, ẹni tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́, ó kígbe ní ohùn rara, 34 “Ó wí pé, kín ni ṣe tàwa tìrẹ, Jesu ará Nasareti? Ìwọ́ wá láti pa wá run bí? Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe, Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.”
35 Jesu sì bá a wí gidigidi, ó wí fun pe,
36 Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì ń bá ara wọn sọ wí pé, “Irú ẹ̀kọ́ kín ni èyí? Nítorí pẹ̀lú àṣẹ àti agbára ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí àìmọ́ wí, wọ́n sì jáde kúrò.” 37 [~21~]Òkìkí rẹ̀ sì kàn níbi gbogbo ní agbègbè ilẹ̀ náà yíká.
38 [~22~]Nígbà tí ó sì dìde kúrò nínú Sinagọgu, ó sì wọ̀ ilé Simoni lọ; ibà sì ti dá ìyá ìyàwó Simoni dùbúlẹ̀, wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ nítorí rẹ̀. 39 Ó sì súnmọ́ ọ, ó bá ibà náà wí; ibà sì náà sì fi sílẹ̀. O sì dìde lọ́gán, ó ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.
40 Nígbà tí oòrùn sì ń wọ̀, àwọn ènìyàn gbe àwọn aláìsàn, tó ní onírúurú àìsàn wá sọ́dọ̀ Jesu; ó sì fi ọwọ́ lé olúkúlùkù wọn, ó sì mú wọn láradá. 41 Àwọn ẹ̀mí èṣù sì jáde lára ẹni púpọ̀ pẹ̀lú, wọ́n ń kígbe, wí pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run!” Ó sì ń bá wọn wí kò sì jẹ́ kí wọn kí ó fọhùn, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé Òun ni Kristi náà.
42 [~23~]Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, Jesu sì jáde lọ, ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀. Ìjọ ènìyàn sì ń wá a kiri, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì dá a dúró, nítorí kí ó má ba à lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn. 43 Ṣùgbọ́n ó sì wí fún wọn pé,
4:1 Mt 4.1-11; Mk 1.12-13.
4:2 De 9.9; 1Ọb 19.8.
4:4 De 8.3.
4:6 1Jh 5.19.
4:8 De 6.13.
4:10 Sm 91.11-12.
4:12 De 6.16.
4:13 Lk 22.28.
4:14 Mt 4.12; Mk 1.14; Mt 9.26; Lk 4.37.
4:15 Mt 4.23; 9.35; 11.1.
4:16 Mt 13.53-58; Mk 6.1-6; Isa 13.14-16.
4:22 Jh 6.42; 7.15.
4:23 Mk 1.21; 2.1; Jh 4.46.
4:24 Jh 4.44.
4:25 1Ọb 17.1,8-16; 18.1; Jk 5.17-18.
4:27 2Ọb 5.1-14.
4:29 Ap 7.58; Nu 15.35.
4:30 Jh 8.59; 10.39.
4:31 Mk 1.21-28.
4:32 Mt 7.28; 13.54; 22.33; Mk 11.18; Jh 7.46.
4:37 Lk 4.14; 5.15; Mt 9.26.
4:38 Mt 8.14-17; Mk 1.29-34.
4:42 Mk 1.35-38.
4:44 Mt 4.23; Mk 1.39; Mt 9.35.