1 [~1~]Àjọ ọdún àìwúkàrà tí à ń pè ní Ìrékọjá sì kù fẹ́ẹ́rẹ́. 2 Àti àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà tí wọn ìbá gbà pa á; nítorí tí wọn ń bẹ̀rù àwọn ènìyàn. 3 Satani sì wọ inú Judasi, tí à ń pè ní Iskariotu, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá. 4 Ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n, ó lọ láti bá àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ gbèrò pọ̀, bí òun yóò tí fi í lé wọn lọ́wọ́. 5 [~2~]Wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì bá a dá májẹ̀mú láti fún un ní owó. 6 Ó sì gbà; ó sì ń wá àkókò tí ó wọ̀, láti fi í lé wọn lọ́wọ́ láìsí ariwo.
7 [~3~][~4~]Ọjọ́ àìwúkàrà pé, nígbà tí wọ́n ní láti pa ọ̀dọ́-àgùntàn ìrékọjá fún ìrúbọ. 8 [~5~]Ó sì rán Peteru àti Johanu, wí pé,
9 Wọ́n sì wí fún un pé, “Níbo ni ìwọ ń fẹ́ kí á pèsè sílẹ̀?”
10 Ó sì wí fún wọn pé,
13 Wọ́n sì lọ wọ́n sì bá a gẹ́gẹ́ bí ó tí sọ fún wọn, wọ́n sì pèsè ìrékọjá sílẹ̀.
14 [~6~]Nígbà tí àkókò sì tó, ó jókòó àti àwọn aposteli pẹ̀lú rẹ̀. 15 [~7~]Ó sì wí fún wọn pé,
17 [~9~]Ó sì gba ago, nígbà tí ó sì ti dúpẹ́, ó wí pé,
19 [~11~]Ó sì mú àkàrà, nígbà tí ó sì ti dúpẹ́ ó bù ú, ó sì fi fún wọn, ó wí pé,
20 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́, ó sì mú ago wáìnì, ó wí pé,
24 [~13~]Ìjà kan sì ń bẹ láàrín wọn, ní ti ẹni tí a kà sí olórí nínú wọn. 25 [~14~]Ó sì wí fún wọn pé,
31 [~20~]Olúwa sì wí pé,
33 [~22~]Ó sì wí fún un pé, “Olúwa, mo múra tán láti bá ọ lọ sínú túbú, àti sí ikú.”
34 Ó sì wí pé,
35 [~23~]Ó sì wí fún wọn pé,
36 [~24~]Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé,
38 Wọ́n sì wí pé, “Olúwa, sá wò ó, idà méjì ń bẹ níhìn-ín yìí!”
39 [~26~]Ó sì jáde, ó sì lọ bí ìṣe rẹ̀ sí òkè olifi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. 40 [~27~][~28~]Nígbà tí ó wà níbẹ̀, ó wí fún wọn pé,
45 Nígbà tí ó sì dìde kúrò ní ibi àdúrà, tí ó sì tọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, ó bá wọn, wọ́n ń sùn nítorí ìbànújẹ́ ti mu kí ó rẹ̀ wọ́n. 46 Ó sì wí fún wọn pé,
47 [~30~]Bí ó sì ti ń sọ lọ́wọ́, kíyèsi i, ọ̀pọ̀ ènìyàn, àti ẹni tí a ń pè ní Judasi, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá, ó ṣáájú wọn, ó súnmọ́ Jesu láti fi ẹnu kò ó ní ẹnu. 48 Jesu sì wí fún un pé,
49 [~31~]Nígbà tí àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ń wo bí nǹkan yóò ti jásí, wọ́n bi í pé, “Olúwa kí àwa fi idà sá wọn?” 50 Ọ̀kan nínú wọn sì fi idà ṣá ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì gé etí ọ̀tún rẹ̀ sọnù.
51 Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn ó wí pé,
52 Jesu wí fún àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tẹmpili, àti àwọn alàgbà, tí wọ́n jáde tọ̀ ọ́ wá pé,
54 [~33~]Wọ́n sì gbá a mú, wọ́n sì fà á lọ, wọ́n sì mú un wá sí ilé olórí àlùfáà. Ṣùgbọ́n Peteru tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní òkèrè. 55 Nígbà tí wọ́n sì ti dáná láàrín àgbàlá, tí wọ́n sì jókòó pọ̀, Peteru jókòó láàrín wọn. 56 [~34~]Ọmọbìnrin kan sì rí i bí ó ti jókòó níbi ìmọ́lẹ̀ iná náà, ó sì tẹjúmọ́ ọn, ó ní, “Eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀.”
57 Ṣùgbọ́n, ó wí pé, “Obìnrin yìí, èmi kò mọ̀ ọ́n.”
58 Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ẹlòmíràn sì rí i, ó ní, “Ìwọ pẹ̀lú wà nínú wọn.”
59 Ó sì tó bí i wákàtí kan síbẹ̀ ẹlòmíràn tẹnumọ́ ọn, wí pé, “Nítòótọ́ eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀: nítorí ará Galili ní í ṣe.”
60 Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Ọkùnrin yìí, èmi kò mọ ohun tí ìwọ ń wí!” Lójúkan náà, bí ó tí ń wí lẹ́nu, àkùkọ kọ! 61 [~35~]Olúwa sì yípadà, ó wo Peteru. Peteru sì rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí fún un pé,
63 [~36~]Ó sì ṣe, àwọn ọkùnrin tí wọ́n mú Jesu, sì fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n lù ú. 64 Nígbà tí wọ́n sì dì í ní ojú, wọ́n lù ú níwájú, wọ́n ń bi í pé, “Sọtẹ́lẹ̀! Ta ni ó lù ọ́?” 65 Wọ́n sì sọ ọ̀pọ̀ ohun búburú mìíràn sí i, láti fi ṣe ẹlẹ́yà.
66 [~37~]Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ìjọ àwọn alàgbà àwọn ènìyàn péjọpọ̀, àti àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, wọ́n sì fà á lọ sí àjọ wọn, wọ́n ń wí pé, 67 [~38~]“Bí ìwọ bá jẹ́ Kristi náà? Sọ fún wa!”
70 [~39~]Gbogbo wọn sì wí pé, “Ìwọ ha ṣe Ọmọ Ọlọ́run bí?”
71 Wọ́n sì wí pé, “Ẹ̀rí wo ni àwa tún ń fẹ́ àwa tìkára wa sá à ti gbọ́ lẹ́nu rẹ̀!”
<- Luku 21Luku 23 ->22:1 Mt 26.2-5; Mk 14.1-2; Jh 11.47-53.
22:5 Mt 26.14-16; Mk 14.10-11; Jh 13.2.
22:7 Mt 26.17-19; Mk 14.12-16.
22:7 El 12.18-20; De 16.5-8.
22:8 Ap 3.1; Lk 19.29.
22:14 Mt 26.20; Mk 14.17; Jh 13.17.
22:15 Lk 12.49-50.
22:16 Lk 14.15.
22:17 Mt 26.27; Mk 14.23; 1Kọ 10.16.
22:18 Mt 26.29; Mk 14.25.
22:19 Mt 26.26; Mk 14.22; 1Kọ 10.16; 11.23-26; Lk 9.16.
22:21 Mt 26.21-24; Mk 14.18-21; Sm 41.9; Jh 13.21-30.
22:24 Lk 9.46; Mk 9.34.
22:25 Mt 20.25-28; Mk 10.42-45; Jh 13.3-16.
22:26 Lk 9.48.
22:28 Mt 19.28.
22:28 Lk 4.13; Hb 2.18; 4.15.
22:29 Mk 14.24; Hb 9.20.
22:30 Mk 10.37; If 3.21; 20.4.
22:31 Jb 1.6-12; Am 9.9.
22:32 Jh 17.15; 21.15-17.
22:33 Mt 26.33-35; Mk 14.29-31; Jh 13.37-38.
22:35 Lk 10.4; Mt 10.9.
22:36 Lk 22.49-50.
22:37 Isa 53.12.
22:39 Mt 26.30; Mk 14.26; Jh 18.1.
22:40 Mt 26.36-46; Mk 14.32-42; Hb 5.7-8.
22:40 Lk 11.4.
22:42 Mk 10.38; Jh 18.11; 5.30.
22:47 Mt 26.47-56; Mk 14.43-49; Jh 18.3-11.
22:49 Lk 22.38.
22:53 Lk 19.47.
22:54 Mt 26.57-58; Mk 14.53-54; Jh 18.12-16.
22:56 Mt 26.69-75; Mk 14.66-72; Jh 18.16-18,25-27.
22:61 Lk 7.13; 22.34.
22:63 Mt 26.67-68; Mk 14.65; Jh 18.22-24.
22:66 Mt 26.57; Mk 14.53; Lk 22.54.
22:67 Mt 26.63-66; Mk 14.61-64; Jh 18.19-21.
22:70 Lk 23.3; Mt 27.11.