1 [~1~]Ní ọjọ́ kan, bí ó ti ń kọ́ àwọn ènìyàn ní tẹmpili tí ó sì ń wàásù ìyìnrere, àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, pẹ̀lú àwọn àgbàgbà dìde sí i. 2 [~2~]Wọ́n sì wí fún un pé, “Sọ fún wa, àṣẹ wo ni ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Tàbí ta ni ó fún ọ ní àṣẹ yìí?”
3 Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé,
5 Wọ́n sì bá ara wọn gbèrò pé, “Bí àwa bá wí pé, ‘Láti ọ̀run wá ni,’ òun yóò wí pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà á gbọ́?’ 6 [~3~]Ṣùgbọ́n bí àwa bá sì wí pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn,’ gbogbo ènìyàn ni yóò sọ wá ní òkúta, nítorí wọ́n gbàgbọ́ pé, wòlíì ni Johanu.”
7 Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Àwa kò mọ̀ ibi tí ó ti wá.”
8 Jesu sì wí fún wọn pé,
9 [~4~][~5~]Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí í pa òwe yìí fún àwọn ènìyàn pé,
13
14
17 [~7~]Nígbà tí ó sì wò wọ́n, ó ní,
19 [~9~]Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà láti mú un ní wákàtí náà; ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rù àwọn ènìyàn, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé, ó pa òwe yìí mọ́ wọn.
20 [~10~]Wọ́n sì ń ṣọ́ ọ, wọ́n sì rán àwọn ayọ́lẹ̀wò tí wọ́n ṣe ara wọn bí ẹni pé olóòtítọ́ ènìyàn, kí wọn ba à lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú, kí wọn ba à lè fi í lé agbára àti àṣẹ Baálẹ̀ lọ́wọ́. 21 [~11~]Wọ́n sì bí i, pé, “Olùkọ́ àwa mọ̀ pé, ìwọ a máa sọ̀rọ̀ fún ni, ìwọ a sì máa kọ́ni bí ó ti tọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì í ṣe ojúsàájú ẹnìkan ṣùgbọ́n ìwọ ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run lóòtítọ́. 22 Ǹjẹ́ ó tọ́ fún wa láti máa san owó òde fún Kesari, tàbí kò tọ́?”
23 Ṣùgbọ́n ó kíyèsi àrékérekè wọn, ó sì wí fún wọn pé, 24
25 [~12~]Ó sì wí fún wọn pé,
26 Wọn kò sì lè gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú níwájú àwọn ènìyàn: ẹnu sì yà wọ́n sí ìdáhùn rẹ̀, wọ́n sì pa ẹnu wọn mọ́.
27 [~13~][~14~]Àwọn Sadusi kan sì tọ̀ ọ́ wá, àwọn tí wọ́n ń wí pé àjíǹde òkú kò sí wọ́n sì bi í, 28 [~15~]wí pé, “Olùkọ́, Mose kọ̀wé fún wa pé, Bí arákùnrin ẹnìkan bá kú, ní àìlọ́mọ, tí ó sì ní aya, kí arákùnrin rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó, kí ó lè gbé irú-ọmọ dìde fún arákùnrin rẹ̀. 29 Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan ti wà; èkínní gbé ìyàwó, ó sì kú ní àìlọ́mọ. 30 Èkejì sì ṣú u lópó: òun sì kú ní àìlọ́mọ. 31 Ẹ̀kẹta sì ṣú u lópó: gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn méjèèje pẹ̀lú: wọn kò sì fi ọmọ sílẹ̀, wọ́n sì kú. 32 Nígbẹ̀yìn pátápátá obìnrin náà kú pẹ̀lú. 33 Ǹjẹ́ ní àjíǹde òkú, aya ti ta ni yóò ha ṣe nínú wọn? Nítorí àwọn méjèèje ni ó sá à ni í ní aya.”
34 Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé,
39 [~17~]Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn akọ̀wé dá a lóhùn, pé, “Olùkọ́ ìwọ wí rere!” 40 [~18~]Wọn kò sì jẹ́ bi í léèrè ọ̀rọ̀ kan mọ́.
41 [~19~]Ó sì wí fún wọn pé,
45 [~20~]Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní etí gbogbo ènìyàn pé, 46
20:1 Mt 21.23-27; Mk 11.27-33.
20:2 Jh 2.18.
20:6 Mt 14.5; Lk 7.29.
20:9 Mt 21.33-46; Mk 12.1-12.
20:9 Isa 5.1-7; Mt 25.14.
20:16 Ap 13.46; 18.6; 28.28.
20:17 Sm 118.22-23; Ap 4.11; 1Pt 2.6-7.
20:18 Isa 8.14-15.
20:19 Lk 19.47.
20:20 Mt 22.15-22; Mk 12.13-17.
20:21 Jh 3.2.
20:25 Mt 22.23-33; Mk 12.18-27.
20:27 Mt 22.23-33; Mk 12.18-27.
20:27 Ap 4.1-2; 23.6-10.
20:28 De 25.5.
20:37 Ek 3.6.
20:39 Mk 12.28.
20:40 Mk 12.34; Mt 22.46.
20:41 Mt 22.41-45; Mk 12.35-37; Sm 110.1.
20:45 Mk 12.38-40; Mt 23.6-7; Lk 11.43; 14.7-11.