1
3 [~2~]“ ‘Ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ bọ̀wọ̀ fún ìyá àti baba rẹ̀, kí ẹ sì ya ọjọ́ ìsinmi mi sí mímọ́. Èmi ni
4 [~3~]“ ‘Ẹ má ṣe yípadà tọ ère òrìṣà lẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ rọ ère òrìṣà idẹ fún ara yín. Èmi ni
5 “ ‘Nígbà tí ẹ̀yin bá sì rú ẹbọ àlàáfíà sí
9 [~4~]“ ‘Nígbà tí ẹ̀yin bá kórè nǹkan oko yín, kí ẹ̀yin kí ó fi díẹ̀ sílẹ̀ láìkórè ní àwọn igun oko yín, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ ṣa ẹ̀ṣẹ́ (nǹkan oko tí ẹ ti gbàgbé tàbí tí ó bọ́ sílẹ̀). 10 Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ kórè oko yín tan pátápátá, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣa èso tí ó rẹ̀ bọ́ sílẹ̀ nínú ọgbà àjàrà yín. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn aláìní àti fún àwọn àlejò. Èmi ni
11 [~5~]“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè.
12 [~6~]“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fi orúkọ mi búra èké, kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ ba orúkọ Ọlọ́run rẹ jẹ́. Èmi ni
13 [~7~]“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ rẹ́ aládùúgbò rẹ jẹ bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ jà á lólè.
14 [~8~]“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣépè lé adití, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ fi ohun ìdìgbòlù sí iwájú afọ́jú, ṣùgbọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run rẹ. Èmi ni
15 [~9~]“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po, má ṣe ojúsàájú sí ẹjọ́ tálákà, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ gbé ti ọlọ́lá lẹ́yìn, ṣùgbọ́n fi òdodo ṣe ìdájọ́, àwọn aládùúgbò rẹ.
16 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ máa ṣèyíṣọ̀hún bí olóòfófó láàrín àwọn ènìyàn rẹ.
17 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ kórìíra arákùnrin rẹ lọ́kàn rẹ, bá aládùúgbò rẹ wí, kí o má ba à jẹ́ alábápín nínú ẹ̀bi rẹ̀.
18 [~10~]“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbẹ̀san: má sì ṣe bínú sí èyíkéyìí nínú àwọn ènìyàn rẹ. Ṣùgbọ́n, kí ìwọ kí ó fẹ́ ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ. Èmi ni
19 [~11~]“ ‘Máa pa àṣẹ mi mọ́.
20 “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá obìnrin tí ó jẹ́ ẹrú lòpọ̀, ẹni tí a ti mọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin mìíràn tí a kò sì tí ì rà á padà tàbí sọ ọ́ di òmìnira. Ẹ gbọdọ̀ ṣe ìwádìí kí ẹ sì jẹ wọ́n ní ìyà tó tọ́ ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ pa wọ́n, torí pé kò ì tí ì di òmìnira. 21 Kí ọkùnrin náà mú àgbò kan wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé bí i ẹbọ ẹ̀bi sí
23 “ ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà tí ẹ sì gbin igi eléso, kí ẹ ká èso wọn sí ohun èèwọ̀. Fún ọdún mẹ́ta ni kí ẹ kà á sí èèwọ̀, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́. 24 Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹrin, gbogbo èso wọ̀nyí yóò jẹ́ mímọ́, ọrẹ fún ìyìn
26 [~12~]“ ‘Ẹ má ṣe jẹ ẹrankẹ́ran pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.
27 [~13~]“ ‘Ẹ má ṣe dá òṣù sí àárín orí yín (fífá irun ẹ̀gbẹ́ orí, tí a ó sì dá irun àárín orí sí) tàbí kí ẹ ré orí irùngbọ̀n yín bí àwọn aláìkọlà ti ń ṣe.
28 “ ‘Ẹ má ṣe tìtorí òkú, gé ibi kankan nínú ẹ̀yà ara yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ sín gbẹ́rẹ́ kankan. Èmi ni
29 [~14~]“ ‘Ẹ má ṣe ba ọmọbìnrin yín jẹ́ láti sọ ọ́ di panṣágà, kí ilẹ̀ yín má ba à di ti àgbèrè, kí ó sì kún fún ìwà búburú.
30 [~15~]“ ‘Ẹ gbọdọ̀ máa pa ìsinmi mi mọ́ kí ẹ sì fi ọ̀wọ̀ fún ibi mímọ́ mi. Èmi ni
31 [~16~]“ ‘Ẹ má ṣe tọ abókùúsọ̀rọ̀ tàbí àwọn àjẹ́ lọ, ẹ kò gbọdọ̀ tọ̀ wọ́n lẹ́yìn láti jẹ́ kí wọ́n sọ yín di aláìmọ́. Èmi ni
32 “ ‘Fi ọ̀wọ̀ fún ọjọ́ orí arúgbó, ẹ sì bu ọlá fún àwọn àgbàlagbà kí ẹ sì bẹ̀rù Ọlọ́run yín. Èmi ni
33 [~17~]“ ‘Nígbà tí àjèjì kan bá ń gbé pẹ̀lú yín ní ilẹ̀ yín, ẹ má ṣe ṣe é ní ibi 34 kí àjèjì tí ń gbé pẹ̀lú yín dàbí onílé láàrín yín kí ẹ sì fẹ́ràn rẹ̀ bí i ara yín, torí pé ẹ̀yin ti jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Ejibiti rí. Èmi ni
35 [~18~]“ ‘Ẹ má ṣe lo òsùwọ̀n èké, nígbà tí ẹ bá ń díwọ̀n yálà nípa òsùwọ̀n ọ̀pá, òsùwọ̀n ìwúwo tàbí òsùwọ̀n onínú. 36 Ẹ jẹ́ olódodo pẹ̀lú àwọn òsùwọ̀n yín òsùwọ̀n ìtẹ̀wọ̀n, òsùwọ̀n wíwúwo, òsùwọ̀n ìyẹ̀fun àti òsùwọ̀n nǹkan olómi yín ní láti jẹ́ èyí tí kò ní èrú nínú. Èmi ni
37 “ ‘Ẹ ó sì máa pa gbogbo àṣẹ àti òfin mi mọ́, ẹ ó sì máa ṣe wọ́n. Èmi ni
19:2 Le 11.44,45; 20.7,26; 1Pt 1.16.
19:3 Ek 20.12; De 5.16; Ek 20.8; 23.12; 34.21; 35.23; De 5.12-15.
19:4 Ek 20.4; Le 26.1; De 4.15-19; 27.15.
19:9 Le 23.22; De 24.20,21.
19:11 Ek 20.15,16; De 5.19.
19:12 Ek 20.7; De 5.11; Mt 5.33.
19:13 De 24.15; Jk 5.4.
19:14 De 27.18.
19:15 Ek 23.6; De 1.17.
19:18 Mt 5.43; 19.19; 22.39; Mk 12.31; Lk 10.27; Ro 13.9; Ga 5.14; Jk 2.8.
19:19 De 22.9,11.
19:26 Le 3.17; 7.26,27; 17.10-16; De 12.16,23-25; 18.10.
19:27 Le 21.5; De 14.1.
19:29 De 23.17,18.
19:30 Ek 20.8-11; 23.12; 34.21; 35.2,3; Le 19.3; 26.2; De 5.12-15.
19:31 Le 20.6,27.
19:33 Ek 22.21.
19:35 De 25.13-16; Òw 20.10; El 45.10.