Ìwé Jobu
1 Ọkùnrin kan wà ní ilẹ̀ Usi, orúkọ ẹni tí í jẹ́ Jobu; ọkùnrin náà sì ṣe olóòtítọ́, ó dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó kórìíra ìwà búburú. 2 A sì bi ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta fún un. 3 Ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) àgùntàn, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ìbákasẹ, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) àjàgà ọ̀dá màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì pọ̀; bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin yìí sì pọ̀jù gbogbo àwọn ará ìlà-oòrùn lọ.
4 Àwọn ọmọ rẹ̀ a sì máa lọ í jẹun àsè nínú ilé ara wọn, olúkúlùkù ní ọjọ́ rẹ̀; wọn a sì máa ránṣẹ́ pé arábìnrin wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta láti jẹun àti láti pẹ̀lú wọn. 5 Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ àsè wọn pé yíká, ni Jobu ránṣẹ́ lọ í yà wọ́n sí mímọ́, ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì rú ẹbọ sísun níwọ̀n iye gbogbo wọn; nítorí tí Jobu wí pé: bóyá àwọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣọpẹ́ fún Ọlọ́run lọ́kàn wọn. Bẹ́ẹ̀ ní Jobu máa ń ṣe nígbà gbogbo.
6 Ǹjẹ́ ó di ọjọ́ kan, nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run wá í pé níwájú
8
9 Nígbà náà ni Satani dá
12
13 Ó sì di ọjọ́ kan nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin, tí wọ́n mu ọtí wáìnì nínú ilé ẹ̀gbọ́n wọn ọkùnrin, 14 oníṣẹ́ kan sì tọ Jobu wá wí pé, “Àwọn ọ̀dá màlúù ń tulẹ̀, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì ń jẹ ní ẹ̀gbẹ́ wọn, 15 àwọn ará Sabeani sì kọlù wọ́n, wọ́n sì ń kó wọn lọ pẹ̀lú, wọ́n ti fi idà sá àwọn ìránṣẹ́ pa, èmi nìkan ṣoṣo ní ó sá àsálà láti ròyìn fún ọ.”
16 Bí ó ti ń sọ ní ẹnu; ẹnìkan dé pẹ̀lú tí ó sì wí pé, “Iná ńlá Ọlọ́run ti ọ̀run bọ́ sí ilẹ̀, ó sì jó àwọn àgùntàn àti àwọn ìránṣẹ́; èmi nìkan ṣoṣo ní ó sálà láti ròyìn fún ọ.”
17 Bí ó sì ti ń sọ ní ẹnu, ẹnìkan sì dé pẹ̀lú tí ó wí pé, “Àwọn ará Kaldea píngun sí ọ̀nà mẹ́ta, wọ́n sì kọlù àwọn ìbákasẹ, wọ́n sì kó wọn lọ, pẹ̀lúpẹ̀lú wọ́n sì fi idà sá àwọn ìránṣẹ́ pa; èmi nìkan ṣoṣo ni ó sá àsálà láti ròyìn fún ọ!”
18 Bí ó ti ń sọ ní ẹnu, ẹnìkan dé pẹ̀lú tí ó sì wí pé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti obìnrin ń jẹ, wọ́n ń mu ọtí wáìnì nínú ilé ẹ̀gbọ́n. 19 Sì kíyèsi i, ẹ̀fúùfù ńlá ńlá ti ìhà ijù fẹ́ wá kọlu igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilé, ó sì wó lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà, wọ́n sì kú, èmi nìkan ṣoṣo ni ó yọ láti ròyìn fún ọ.
20 Nígbà náà ni Jobu dìde, ó sì fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya, ó sì fá orí rẹ̀ ó wólẹ̀ ó sì gbàdúrà 21 wí pé,
22 Nínú gbogbo èyí Jobu kò ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi òmùgọ̀ pe Ọlọ́run lẹ́jọ́.
Jobu 2 ->