1 [~1~]Ní kùtùkùtù ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, nígbà tí ilẹ̀ kò tí ì mọ́, ni Maria Magdalene wá sí ibojì, ó sì rí i pé, a ti gbé òkúta kúrò lẹ́nu ibojì. 2 Nítorí náà, ó sáré, ó sì tọ Simoni Peteru àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn wá, ẹni tí Jesu fẹ́ràn, ó sì wí fún wọn pé, “Wọ́n ti gbé Olúwa kúrò nínú ibojì, àwa kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.”
3 [~2~]Nígbà náà ni Peteru àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà jáde, wọ́n sì wá sí ibojì. 4 Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ sáré: èyí ọmọ-ẹ̀yìn náà sì sáré ya Peteru, ó sì kọ́kọ́ dé ibojì. 5 Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti wo inú rẹ̀, ó rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀; ṣùgbọ́n òun kò wọ inú rẹ̀. 6 Nígbà náà ni Simoni Peteru tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ dé, ó sì wọ inú ibojì, ó sì rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀. 7 Àti pé, gèlè tí ó wà níbi orí rẹ̀ kò sì wà pẹ̀lú aṣọ ọ̀gbọ̀ náà, ṣùgbọ́n ó ká jọ ní ibìkan fúnra rẹ̀. 8 Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà, ẹni tí ó kọ́ dé ibojì wọ inú rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì rí i, ó sì gbàgbọ́. 9 [~3~](Nítorí tí wọn kò sá à tí mọ ìwé mímọ́ pé, Jesu ní láti jíǹde kúrò nínú òkú). 10 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà sì tún padà lọ sí ilé wọn.
11 Ṣùgbọ́n Maria dúró létí ibojì lóde, ó ń sọkún: bí ó ti ń sọkún, bẹ́ẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀, ó sì wo inú ibojì. 12 [~4~]Ó sì kíyèsi àwọn angẹli méjì aláṣọ funfun, wọ́n jókòó, ọ̀kan níhà orí àti ọ̀kan níhà ẹsẹ̀, níbi tí òkú Jesu gbé ti sùn sí.
13 [~5~]Wọ́n sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún?”
15 Jesu wí fún un pé,
16 Jesu wí fún un pé,
17 [~7~]Jesu wí fún un pé,
18 [~8~]Maria Magdalene wá, ó sì sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, “Òun ti rí Olúwa!” Àti pé, ó sì ti fi nǹkan wọ̀nyí fún òun.
19 [~9~]Ní ọjọ́ kan náà, lọ́jọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀ nígbà tí alẹ́ lẹ́, tí a sì ti ìlẹ̀kùn ibi tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbé péjọ, nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù, bẹ́ẹ̀ ni Jesu dé, ó dúró láàrín, ó sì wí fún wọn pé,
21 [~10~]Nítorí náà, Jesu sì tún wí fún wọn pé,
24 [~13~]Ṣùgbọ́n Tomasi, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá, tí a ń pè ní Didimu, kò wà pẹ̀lú wọn nígbà tí Jesu dé. 25 Nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù wí fún un pé, “Àwa ti rí Olúwa!”
26 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́jọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì tún wà nínú ilé, àti Tomasi pẹ̀lú wọn: nígbà tí a sì ti ti ìlẹ̀kùn, Jesu dé, ó sì dúró láàrín, ó wí pé,
28 Tomasi dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Olúwa mi àti Ọlọ́run mi!”
29 [~15~]Jesu wí fún un pé,
30 [~16~]Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì mìíràn ni Jesu ṣe níwájú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, tí a kò kọ sínú ìwé yìí. 31 [~17~]Ṣùgbọ́n wọ̀nyí ni a kọ, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́ pé Jesu ní í ṣe Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run, àti pé nípa gbígbàgbọ́, kí ẹ̀yin lè ní ìyè ní orúkọ rẹ̀.
<- Johanu 19Johanu 21 ->20:1 Mt 28.1-8; Mk 16.1-8; Lk 24.1-10.
20:3 Lk 24.11-12.
20:9 Lk 24.26,46.
20:12 Lk 24.4; Mt 28.5; Mk 16.5.
20:13 Jh 20.2.
20:14 Mt 28.9; Jh 21.4.
20:17 Jh 20.27; Mt 28.10; Jh 7.33.
20:18 Lk 24.10,23.
20:19 Lk 24.36-39.
20:21 Jh 17.18; Mt 28.19.
20:22 Ap 2.4,33.
20:23 Mt 16.19; 18.18.
20:24 Jh 11.16.
20:27 Lk 24.40.
20:29 1Pt 1.8.
20:30 Jh 21.25.
20:31 Jh 3.15.
Languages