1 [~1~]Nígbà tí Jesu sì ti sọ nǹkan wọ̀nyí tán, ó jáde pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sókè odò Kidironi, níbi tí àgbàlá kan wà, nínú èyí tí ó wọ̀, Òun àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
2 Judasi, ẹni tí ó fihàn, sì mọ ibẹ̀ pẹ̀lú, nítorí nígbà púpọ̀ ni Jesu máa ń lọ síbẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. 3 [~2~]Nígbà náà ni Judasi, lẹ́yìn tí ó ti gba ẹgbẹ́ ọmọ-ogun, àti àwọn oníṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi wá síbẹ̀ ti àwọn ti fìtílà àti ògùṣọ̀, àti ohun ìjà.
4 [~3~]Nítorí náà bí Jesu ti mọ ohun gbogbo tí ń bọ̀ wá bá òun, ó jáde lọ, ó sì wí fún wọn pé,
5 Wọ́n sì dá a lóhùn wí pé, “Jesu ti Nasareti.”
7 Nítorí náà ó tún bi wọ́n léèrè, wí pé,
8 Jesu dáhùn pé,
10 Nígbà náà ni Simoni Peteru ẹni tí ó ní idà, fà á yọ, ó sì ṣá ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì ké etí ọ̀tún rẹ̀ sọnù. Orúkọ ìránṣẹ́ náà a máa jẹ́ Makọọsi.
11 [~5~]Nítorí náà Jesu wí fún Peteru pé,
12 [~6~]Nígbà náà ni ẹgbẹ́ ọmọ-ogun àti olórí ẹ̀ṣọ́, àti àwọn oníṣẹ́ àwọn Júù mú Jesu, wọ́n sì dè é. 13 Wọ́n kọ́kọ́ fà á lọ sọ́dọ̀ Annasi; nítorí òun ni àna Kaiafa, ẹni tí í ṣe olórí àlùfáà ní ọdún náà. 14 [~7~]Kaiafa sá à ni ẹni tí ó ti bá àwọn Júù gbìmọ̀ pé, ó ṣàǹfààní kí ènìyàn kan kú fún àwọn ènìyàn.
15 [~8~]Simoni Peteru sì ń tọ Jesu lẹ́yìn, àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn kan: ọmọ-ẹ̀yìn náà jẹ́ ẹni mí mọ̀ fún olórí àlùfáà, ó sì bá Jesu wọ ààfin olórí àlùfáà lọ. 16 Ṣùgbọ́n Peteru dúró ní ẹnu-ọ̀nà lóde. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà tí í ṣe ẹni mí mọ̀ fún olórí àlùfáà jáde, ó sì bá olùṣọ́nà náà sọ̀rọ̀, ó sì mú Peteru wọlé.
17 [~9~]Nígbà náà ni ọmọbìnrin náà tí ń ṣọ́ ẹnu-ọ̀nà wí fún Peteru pé, “Ìwọ pẹ̀lú ha ń ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ọkùnrin yìí bí?”
18 Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ àti àwọn aláṣẹ sì dúró níbẹ̀, àwọn ẹni tí ó ti dáná nítorí ti òtútù mú, wọ́n sì ń yáná, Peteru sì dúró pẹ̀lú wọn, ó ń yáná.
19 [~10~]Nígbà náà ni olórí àlùfáà bi Jesu léèrè ní ti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àti ní ti ẹ̀kọ́ rẹ̀.
20 Jesu dá a lóhùn pé,
22 Bí ó sì ti wí èyí tan, ọ̀kan nínú àwọn aláṣẹ tí ó dúró tì í fi ọwọ́ rẹ̀ lu Jesu, pé, “Alábojútó àlùfáà ni ìwọ ń dá lóhùn bẹ́ẹ̀?”
23 [~11~]Jesu dá a lóhùn pé,
25 [~13~]Ṣùgbọ́n Simoni Peteru dúró, ó sì ń yáná. Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Ìwọ pẹ̀lú ha jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀?”
26 Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, tí ó jẹ́ ìbátan ẹni tí Peteru gé etí rẹ̀ sọnù, wí pé, “Èmi ko ha rí ọ pẹ̀lú rẹ̀ ní àgbàlá?” 27 Peteru tún sẹ́: lójúkan náà àkùkọ sì kọ.
28 [~14~]Nígbà náà, wọ́n fa Jesu láti ọ̀dọ̀ Kaiafa lọ sí ibi gbọ̀ngàn ìdájọ́, ó sì jẹ́ kùtùkùtù òwúrọ̀; àwọn tìkára wọn kò wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́, kí wọn má ṣe di aláìmọ́, ṣùgbọ́n kí wọn lè jẹ àsè ìrékọjá. 29 [~15~]Nítorí náà Pilatu jáde tọ̀ wọ́n lọ, ó sì wí pé, “Ẹ̀sùn kín ní ẹ̀yin mú wá fun ọkùnrin yìí?”
30 Wọ́n sì dáhùn wí fún un pé, “Ìbá má ṣe pé ọkùnrin yìí ń hùwà ibi, a kì bá tí fà á lé ọ lọ́wọ́.”
31 Nítorí náà Pilatu wí fún wọn pé, “Ẹ mú un tìkára yín, kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òfin yín.”
33 Nítorí náà, Pilatu tún wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́ lọ, ó sì pe Jesu, ó sì wí fún un pé, “Ìwọ ha ni a pè ni ọba àwọn Júù bí?”
34 Jesu dáhùn pé,
35 Pilatu dáhùn wí pé, “Èmi ha jẹ́ Júù bí? Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè rẹ, àti àwọn olórí àlùfáà ni ó fà ọ́ lé èmi lọ́wọ́, kín ní ìwọ ṣe?”
36 [~17~]Jesu dáhùn wí pé,
37 [~18~]Nítorí náà, Pilatu wí fún un pé, “Ọba ni ọ́ nígbà náà?”
38 [~19~]Pilatu wí fún un pé, “Kín ni òtítọ́?” Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó tún jáde tọ àwọn Júù lọ, ó sì wí fún wọn pé, “Èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀. 39 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ní àṣà kan pé, kí èmi dá ọ̀kan sílẹ̀ fún yín nígbà àjọ ìrékọjá, nítorí náà ẹ ó ha fẹ́ kí èmi dá ọba àwọn Júù sílẹ̀ fún yín bí?”
40 Nítorí náà gbogbo wọn tún kígbe pé, “Kì í ṣe ọkùnrin yìí, bí kò ṣe Baraba!” Ọlọ́ṣà sì ni Baraba.
<- Johanu 17Johanu 19 ->18:1 Mt 26.30,36; Mk 14.26,32; Lk 22.39; 2Sa 15.23.
18:3 Mt 26.47-56; Mk 14.43-50; Lk 22.47-53.
18:4 Jh 6.64; 13.1.
18:9 Jh 17.12; 6.39.
18:11 Mk 10.38; 14.36.
18:12 Mt 26.57; Mk 14.53; Lk 22.54; 3.2.
18:14 Jh 11.49-51.
18:15 Mt 26.58; Mk 14.54; Lk 22.54.
18:17 Mt 26.69-72; Mk 14.66-69; Lk 22.56-58.
18:19 Mt 26.59-66; Mk 14.55-64; Lk 22.67-71.
18:23 Mt 5.39; Ap 23.2-5.
18:24 Jh 18.13; Lk 3.2.
18:25 Mt 26.73-75; Mk 14.70-72; Lk 22.59-62.
18:28 Jh 11.55; Mt 27.1-2; Mk 15.1; Lk 23.1.
18:29 Mt 27.11-14; Mk 15.2-5; Lk 23.2-3.
18:32 Jh 3.14; 12.32.
18:36 Jh 6.15; Mt 26.53.
18:37 Jh 3.32; 8.14,47; 1Jh 4.6.
18:38 Mt 27.15-26; Mk 15.6-15; Lk 23.18-19; Ap 3.14.
Languages