1 [~1~]Nítorí náà, nígbà tí àjọ ìrékọjá ku ọjọ́ mẹ́fà, Jesu wá sí Betani, níbi tí Lasaru wà, ẹni tí ó ti kú, tí Jesu jí dìde kúrò nínú òkú. 2 Wọ́n sì ṣe àsè alẹ́ fún un níbẹ̀. Marta sì ń ṣe ìránṣẹ́, ṣùgbọ́n Lasaru jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó jókòó níbi tábìlì rẹ̀. 3 Nígbà náà ni Maria mú òróró ìkunra nadi, òsùwọ̀n lita kan, àìlábùlà, olówó iyebíye, ó sì ń fi kun Jesu ní ẹsẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ rẹ̀ nù. Ilé sì kún fún òórùn ìkunra náà.
4 [~2~]Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Judasi Iskariotu, ọmọ Simoni ẹni tí yóò fi í hàn, wí pé, 5 “Èéṣe tí a kò ta òróró ìkunra yìí ní ọ̀ọ́dúnrún owó idẹ kí a sì fi fún àwọn tálákà?” 6 [~3~]Ṣùgbọ́n ó wí èyí, kì í ṣe nítorí tí ó náání àwọn tálákà; ṣùgbọ́n nítorí tí ó jẹ́ olè, òun ni ó ni àpò, a sì máa jí ohun tí a fi sínú rẹ̀ láti fi ran ara rẹ lọ́wọ́.
7 [~4~]Nígbà náà ni Jesu wí pé,
9 Nítorí náà, ìjọ ènìyàn nínú àwọn Júù ni ó mọ̀ pé ó wà níbẹ̀; wọ́n sì wá, kì í ṣe nítorí Jesu nìkan, ṣùgbọ́n kí wọn lè rí Lasaru pẹ̀lú, ẹni tí ó ti jí dìde kúrò nínú òkú. 10 [~5~]Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà gbìmọ̀ kí wọn lè pa Lasaru pẹ̀lú, 11 nítorí pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù jáde lọ, wọ́n sì gbà Jesu gbọ́.
12 [~6~]Ní ọjọ́ kejì nígbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó wá sí àjọ gbọ́ pé, Jesu ń bọ̀ wá sí Jerusalẹmu. 13 [~7~]Wọ́n mú imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n sì jáde lọ pàdé rẹ̀, wọ́n sì ń kígbe pé,
16 [~9~]Nǹkan wọ̀nyí kò tètè yé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí a ṣe Jesu lógo, nígbà náà ni wọ́n rántí pé, a kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí nípa rẹ̀ sí i.
17 Nítorí náà, ìjọ ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí o pé Lasaru jáde nínú ibojì rẹ̀, tí ó sì jí i dìde kúrò nínú òkú, jẹ́rìí sí i. 18 Nítorí èyí ni ìjọ ènìyàn sì ṣe lọ pàdé rẹ̀, nítorí tí wọ́n gbọ́ pé ó ti ṣe iṣẹ́ àmì yìí. 19 Nítorí náà àwọn Farisi wí fún ara wọn pé, “Ẹ kíyèsi bí ẹ kò ti lè borí ní ohunkóhun? Ẹ wo bí gbogbo ayé ti ń wọ́ tọ̀ ọ́!”
20 [~10~]Àwọn Giriki kan sì wà nínú àwọn tí ó gòkè wá láti sìn nígbà àjọ, 21 [~11~]Àwọn wọ̀nyí ni ó tọ Filipi wá, ẹni tí í ṣe ará Betisaida tí Galili, wọ́n sì ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, pé, “Alàgbà, àwa ń fẹ́ rí Jesu!” 22 Filipi wá, ó sì sọ fún Anderu; Anderu àti Filipi wá, wọ́n sì sọ fún Jesu.
23 [~12~]Jesu sì dá wọn lóhùn pé,
27 [~15~]
30 Jesu sì dáhùn wí pé,
34 [~19~]Nítorí náà àwọn ìjọ ènìyàn dá a lóhùn pé, “Àwa gbọ́ nínú òfin pé, Kristi wà títí láéláé, ìwọ ha ṣe wí pé,
35 [~20~]Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé,
37 Ṣùgbọ́n bí ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì tó báyìí lójú wọn, wọn kò gbà á gbọ́. 38 [~22~]Kí ọ̀rọ̀ wòlíì Isaiah lè ṣẹ, èyí tí ó sọ pé,
39 Nítorí èyí ni wọn kò fi lè gbàgbọ́, nítorí Isaiah sì tún sọ pé,
42 [~25~]Síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nínú àwọn olórí gbà á gbọ́ pẹ̀lú; ṣùgbọ́n nítorí àwọn Farisi wọn kò jẹ́wọ́ rẹ̀, kí a má ba à yọ wọ́n kúrò nínú Sinagọgu, 43 nítorí wọ́n fẹ́ ìyìn ènìyàn ju ìyìn ti Ọlọ́run lọ.
44 [~26~]Jesu sì kígbe ó sì wí pé,
47 [~29~]
12:1 Mt 26.6-13; Mk 14.3-9; Lk 7.37-38.
12:4 Jh 6.71; 13.26.
12:6 Lk 8.3.
12:7 Jh 19.40.
12:10 Mk 14.1.
12:12 Mt 21.4-9; Mk 11.7-10; Lk 19.35-38.
12:13 Sm 118.25; Jh 1.49.
12:15 Sk 9.9.
12:16 Mk 9.32; Jh 2.22.
12:20 Jh 7.35; Ap 11.20.
12:21 Jh 1.44; 6.5.
12:23 Jh 13.1; 17.1; Mk 14.35,41.
12:24 1Kọ 15.36.
12:25 Mt 10.39; Mk 8.35; Lk 9.24; 14.26.
12:27 Jh 11.33; Mt 26.38; Mk 14.34.
12:28 Mk 1.11; 9.7.
12:31 Jh 16.11; 2Kọ 4.4; Ef 2.2.
12:32 Jh 3.14; 8.28.
12:34 Sm 110.4; Isa 9.7; El 37.25; Da 7.14.
12:35 Jh 7.33; 9.4; Ef 5.8; 1Jh 2.11.
12:36 Lk 16.8; Jh 8.59.
12:38 Isa 53.1; Ro 10.16.
12:40 Isa 6.10; Mt 13.14.
12:41 Isa 6.1; Lk 24.27.
12:42 Jh 9.22; Lk 6.22.
12:44 Mt 10.40; Jh 5.24.
12:45 Jh 14.9.
12:46 Jh 1.4; 8.12; 9.5.
12:47 Jh 3.17.
12:48 Mt 10.14-15.