1 Ó sì ṣe, nígbà tí a kó Jerusalẹmu, ní ọdún kẹsànán Sedekiah, ọba Juda, nínú oṣù kẹwàá, Nebukadnessari ọba Babeli gbógun ti Jerusalẹmu pẹ̀lú gbogbo ogun rẹ̀, wọ́n sì dó tì í. 2 Ní ọjọ́ kẹsànán, oṣù kẹrin ọdún kọkànlá Sedekiah, ni a wó odi ìlú náà. 3 Nígbà náà ni gbogbo àwọn ìjòyè ọba Babeli wá, wọ́n sì jókòó ní àárín ẹnu ibodè, àní Nergali-Ṣareseri ti Samgari, Nebo-Sarsikimu olórí ìwẹ̀fà, Nergali-Ṣareseri, olórí amòye, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìjòyè ọba Babeli yóò kú. 4 Nígbà tí Sedekiah ọba Juda àti àwọn ọmọ-ogun rí wọn, wọ́n sá, wọ́n kúrò ní ìlú ní alẹ́, wọ́n gba ọ̀nà ọgbà ọba lọ láàrín ẹnu ibodè pẹ̀lú odi méjì, wọ́n dojúkọ aginjù.
5 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ogun Babeli lé wọn, wọ́n bá Sedekiah láàrín aginjù Jeriko. Wọ́n mú un ní ìgbèkùn, wọ́n sì mú u tọ Nebukadnessari ọba Babeli àti Ribla ní ilẹ̀ Hamati, níbi tí wọ́n ti ṣe ìdájọ́ rẹ̀. 6 Níbẹ̀ ní Ribla, ni ọba Babeli ti dúńbú àwọn ọmọ Sedekiah lójú rẹ̀, tí ó sì tún pa gbogbo àwọn ọlọ́lá ilẹ̀ Juda. 7 Nígbà náà ni ó fọ́ ojú Sedekiah, ó sì dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n láti gbé e lọ sí ilẹ̀ Babeli.
8 Àwọn Babeli dáná sun ààfin ọba àti ilé àwọn ènìyàn, wọ́n sì wó odi Jerusalẹmu. 9 Nebusaradani olórí àwọn ọmọ-ogun mú lọ sí ìgbèkùn Babeli pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó ṣẹ́kù nínú ìlú. 10 Ṣùgbọ́n Nebusaradani olórí ogun fi àwọn aláìní sílẹ̀ ní Juda, àwọn tí kò ní ohun kankan ní àkókò náà, ó fún wọn ní ọgbà àjàrà àti oko.
11 Nísinsin yìí, Nebukadnessari ọba àwọn Babeli pàṣẹ lórí Jeremiah, láti ọ̀dọ̀ Nebusaradani olórí ogun wá wí pé: 12 “Ẹ gbé e, kí ẹ sì bojútó o. Ẹ má ṣe ṣe ohun búburú fún un, ṣùgbọ́n ohunkóhun tó bá béèrè ni kí ẹ fi fún un.” 13 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú, Nebusaradani balógun ìṣọ́, àti Nebusaradani olórí ìwẹ̀fà, àti Nergali-Ṣareseri, olórí amòye àti gbogbo àwọn ìjòyè ọba Babeli, 14 ránṣẹ́ láti mú Jeremiah kúrò nínú túbú. Wọ́n gbé e lọ fún Gedaliah ọmọ Ahikamu ọmọ Ṣafani láti mú padà lọ sí ilé àti máa wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.
15 Nígbà tí Jeremiah wà nínú túbú, ọ̀rọ̀