1 Lẹ́yìn ikú Ehudu, àwọn ènìyàn Israẹli sì tún ṣẹ̀, wọ́n ṣe ohun tí ó burú ní ojú
4 Debora, wòlíì obìnrin, aya Lapidoti ni olórí àti aṣíwájú àwọn ará Israẹli ní àsìkò náà. 5 Òun a máa jókòó ṣe ìdájọ́ ní abẹ́ igi ọ̀pẹ tí a sọ orúkọ rẹ̀ ní ọ̀pẹ Debora láàrín Rama àti Beteli ní ilẹ̀ òkè Efraimu, àwọn ará Israẹli a sì máa wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti yanjú èdè-àìyedè tí wọ́n bá ní sí ara wọn, tàbí láti gbọ́ ohùn
8 Baraki sì dá a lóhùn pé, “Èmi yóò lọ tí ìwọ ó bá bá mi lọ, ṣùgbọ́n tí ìwọ kì yóò bá bá mi lọ, èmi kì yóò lọ.”
9 Debora dá a lóhùn pé, “ó dára, èmi yóò bá ọ lọ. Ṣùgbọ́n ọlá ìṣẹ́gun tí o ń lọ yìí kò ní jẹ́ tìrẹ, nítorí
11 Ǹjẹ́ Heberi ọmọ Keni, ti ya ara rẹ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Keni, àní àwọn ọmọ Hobabu, àna Mose, ó sì pa àgọ́ rẹ̀ títí dé ibi igi óákù Saananimu, tí ó wà ni agbègbè Kedeṣi.
12 Nígbà tí a sọ fún Sisera pé Baraki ọmọ Abinoamu ti kó ogun jọ sí òkè Tabori, 13 Sisera kó gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun irin rẹ̀ tí ṣe ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (900) àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, láti Haroseti tí àwọn orílẹ̀-èdè wá sí odò Kiṣoni.
14 Debora sì wí fún Baraki pé, “Lọ! Lónìí ni
16 Baraki àti àwọn ogun rẹ̀ sì lé àwọn ọ̀tá náà, àwọn ọmọ-ogun orílẹ̀ àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn títí dé Haroseti ti àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo ogun Sisera sì ti ojú idà ṣubú, kò sí ọ̀kan tí ó lè sálà tàbí tí ó wà láààyè. 17 Ṣùgbọ́n Sisera ti fi ẹsẹ̀ sálọ sí àgọ́ Jaeli aya Heberi ẹ̀yà Keni: nítorí ìbá dá ọ̀rẹ́ àlàáfíà wà láàrín Jabini ọba Hasori àti ìdílé Heberi ti ẹ̀yà Keni.
18 Jaeli sì jáde síta láti pàdé Sisera, ó sì wí fún un pé, “Wọlé sínú àgọ́ mi,
19 Sisera wí pé, “Òrùngbẹ ń gbẹ́ mí, jọ̀wọ́ fún mi ní omi mu.” Ó sì ṣí awọ wàrà kan, ó sì fún un mu ó sì tún daṣọ bò ó padà.
20 Sisera sọ fún Jaeli pé, “Kí ó dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, àti pé bí ẹnikẹ́ni bá béèrè bóyá òun wà níbẹ̀ kí ó sọ pé, ‘Kò sí ẹnìkankan ní ibẹ̀.’ ”
21 Ṣùgbọ́n Jaeli ìyàwó Heberi mú ìṣó àgọ́ tí ó mú àti òòlù ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì yọ́ wọ inú ibi tí ó sùn, nígbà tí ó ti sùn fọnfọn, nígbà náà ni ó kan ìṣó náà mọ́ òkè ìpéǹpéjú rẹ̀, ó sì wọlé ṣinṣin, ó sì kú.
22 Nígbà tí Baraki dé bí ó ti ń lépa Sisera, Jaeli láti pàdé rẹ̀, wá, èmi yóò fi ẹni tí ìwọ ń wá hàn ọ́, báyìí ni ó tẹ̀lé e wọ inú àgọ́ lọ, kíyèsi Sisera dùbúlẹ̀ síbẹ̀ pẹ̀lú ìṣó àgọ́ ní agbárí rẹ̀ tí a ti kàn mọ́lẹ̀ ṣinṣin tí ó sì ti kú.
23 Ní ọjọ́ náà ni Ọlọ́run ṣẹ́gun Jabini ọba àwọn ará Kenaani ní iwájú àwọn ẹ̀yà Israẹli. 24 Ọwọ́ àwọn ọmọ Israẹli sì le, ó sì ń lágbára síwájú àti síwájú sí i lára Jabini ọba Kenaani, títí wọ́n fi run òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀.
<- Onidajọ 3Onidajọ 5 ->