1 Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ní àkókò ìkórè alikama, Samsoni mú ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan láti bẹ ìyàwó rẹ̀ wò. Ó ní, “Èmi yóò wọ yàrá ìyàwó mi lọ.” Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ kò gbà á láààyè láti wọlé.
2 Baba ìyàwó dá a lóhùn pé, “Ó dá mi lójú pé o kórìíra rẹ̀, torí náà mo ti fi fún ọ̀rẹ́ rẹ, ṣe bí àbúrò rẹ̀ obìnrin kò ha lẹ́wà jùlọ? Fẹ́ ẹ dípò rẹ̀.”
3 Samsoni dáhùn pé, “Ní àkókò yìí tí mo bá ṣe àwọn Filistini ní ibi èmi yóò jẹ́ aláìjẹ̀bi.” 4 Samsoni sì jáde lọ, ó mú ọ̀ọ́dúnrún (300) kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ó so ìrù wọn mọ́ ara wọn ní méjì méjì. Ó mú ètùfù iná, ó so ó mọ́ àwọn ìrù tí ó so pọ̀. 5 Ó fi iná ran àwọn ètùfù tí ó so náà, ó sì jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́ lọ sínú àwọn oko ọkà àwọn Filistini. Ó jó àwọn pòpóòrò ọkà tí ó dúró àti àwọn tí a dì ní ìtí, ìtí, pẹ̀lú àwọn ọgbà àjàrà àti olifi.
6 Nígbà tí àwọn Filistini béèrè pé, “Ta ni ó ṣe èyí?” Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Samsoni ará Timna ni, nítorí a gba ìyàwó rẹ̀ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀.”
9 Àwọn ará Filistini sì dìde ogun sí Juda, wọ́n ti tan ara wọn ká sí agbègbè Lehi. 10 Àwọn ọkùnrin Juda sì béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ fi wá gbóguntì wá?”
11 Nígbà náà ni ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọkùnrin láti Juda sọ̀kalẹ̀ lọ sí ihò àpáta nínú àpáta Etamu, wọ́n sì sọ fún Samsoni pé, “Kò ti yé ọ pé àwọn Filistini ní ń ṣe alákòóso lórí wa? Kí ni o ṣe sí wa?”
12 Wọ́n wí pé, “Àwa wá láti dè ọ́, kí a sì fi ọ́ lé àwọn Filistini lọ́wọ́.”
13 “Àwa gbà,” ni ìdáhùn wọn. “Àwa yóò kàn dè ọ́, àwa yóò sì fi ọ́ lé wọn lọ́wọ́, àwa kì yóò pa ọ́.” Wọ́n sì dé pẹ̀lú okùn tuntun méjì, wọ́n sì mú u jáde wá láti ihò àpáta náà. 14 Bí ó ti súnmọ́ Lehi, àwọn Filistini ń pariwo bí wọ́n ṣe ń tò bọ̀. Ẹ̀mí
16 Samsoni sì wí pé,
18 Nítorí tí òǹgbẹ gbẹ ẹ́ gidigidi, ó ké pe
20 Samsoni ṣe ìdájọ́ Israẹli fún ogún ọdún ní àkókò àwọn ará Filistini.
<- Onidajọ 14Onidajọ 16 ->