1 [~1~]Ní ọdún kẹrìnlá ìjọba Hesekiah, Sennakeribu ọba Asiria kọlu gbogbo àwọn ìlú olódi ní ilẹ̀ Juda ó sì kó gbogbo wọn. 2 Lẹ́yìn náà, ọba Asiria rán olórí ogun rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ-ogun láti Lakiṣi sí ọba Hesekiah ní Jerusalẹmu. Nígbà tí ọ̀gágun náà dúró níbi ojúṣàn adágún ti apá òkè, ní ojú ọ̀nà sí pápá alágbàfọ̀, 3 Ṣebna Eliakimu ọmọ Hilkiah alábojútó ààfin, Ṣebna akọ̀wé, àti Joah ọmọ Asafu akọ̀wé jáde lọ pàdé rẹ̀.
4 Ọ̀gágun náà sọ fún wọn wí pé, “Ẹ sọ fún Hesekiah,
11 Lẹ́yìn náà ni Eliakimu, Ṣebna àti Joah sọ fún ọ̀gágun náà pé, “Jọ̀wọ́ máa bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè Aramaiki, nítorí pé àwa gbọ́ ọ. Má ṣe bá wa sọ̀rọ̀ ní èdè Heberu ní etí àwọn ènìyàn tí ó wà lórí ògiri mọ́.”
12 Ṣùgbọ́n aláṣẹ dáhùn pé, “Ṣé fún ọ̀gá rẹ àti ìwọ nìkan ní ọ̀gá mi rán mi sí láti sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí kì í sì í ṣe fún àwọn ọkùnrin tí ó jókòó lórí odi ni gẹ́gẹ́ bí ìwọ, ni yóò ní láti jẹ ìgbẹ́ ará wọn kí wọ́n sì mu ìtọ̀ ará wọn?”
13 Lẹ́yìn náà ni ọ̀gágun náà dìde tí ó sì ké síta ní èdè Heberu pé, “Ẹ gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ọba ńlá, ọba Asiria! 14 Ohun tí ọba wí nìyìí, Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah tàn yín jẹ. Òun kò le è gbà yín sílẹ̀! 15 Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah rọ̀ yín láti gbẹ́kẹ̀lé
16 “Ẹ má ṣe tẹ́tí sí Hesekiah. Ohun tí ọba Asiria wí nìyìí. Ẹ fi ẹ̀bùn bá mi rẹ́, kí ẹ sì jáde tọ̀ mí wá. Lẹ́yìn náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóò sì jẹ nínú àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni yóò sì mu omi nínú kànga rẹ̀, 17 títí tí èmi yóò fi mú un yín lọ sí ilẹ̀ kan tí ó dàbí i tiyín, ilẹ̀ tí ó ní irúgbìn oníhóró àti wáìnì tuntun, ilẹ̀ tí ó ní àkàrà àti ọgbà àjàrà.
18 “Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah ṣì yín lọ́nà nígbà tí ó sọ wí pé, ‘
21 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà dákẹ́ rọ́rọ́ wọn kò sì mú èsì kankan wá, nítorí ọba ti pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe dá a lóhùn.”
22 Lẹ́yìn náà ni Eliakimu ọmọ Hilkiah alákòóso ààfin, Ṣebna akọ̀wé àti Joah ọmọ Asafu akọ̀wé àkọsílẹ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ Hesekiah pẹ̀lú aṣọ wọn ní fífàya, wọ́n sì sọ ohun tí ọ̀gágun ti wí.
<- Isaiah 35Isaiah 37 ->36:1 2Ọb 18.13–20.11; 2Ki 32.1-24.