1 Ọ̀rọ̀
6 “ ‘Nígbà tí mo sì kọjá tí mo rí ọ tó ń jàgùdù nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ, mo sọ fún ọ pé, “Yè!” Nítòótọ́, nígbà tí ìwọ wà nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ pé, “Yè.” 7 Mo mú ọ dàgbà bí ohun ọ̀gbìn inú oko. O ga sókè, o sì dàgbà, o wá di arẹwà jùlọ, ọmú rẹ yọ, irun rẹ gùn, ìwọ tí o wà ní ìhòhò láìfi nǹkan kan bora.
8 “ ‘Nígbà tí mo tún kọjá, tí mo rí ọ, mo rí i pé àsìkò àti nífẹ̀ẹ́ rẹ ti tó, mo fi ìṣẹ́tí aṣọ mi bo ìhòhò rẹ. Mo búra fún ọ, èmi sì bá ọ dá májẹ̀mú ìwọ sì di tèmi, ni
9 “ ‘Nígbà náà ni mo fi omi wẹ ẹ̀jẹ̀ kúrò ní ara rẹ, mo fi ìpara pa ọ́ lára. 10 Mo fi aṣọ oníṣẹ́-ọnà sí ọ lára láti wọ̀ ọ́, mo wọ bàtà aláwọ fún ọ. Mo fi aṣọ funfun gbòò àti aṣọ olówó iyebíye ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́. 11 Mo fi ohun ọ̀ṣọ́ ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́, mo fi ẹ̀gbà ọwọ́ sí ọ ní ọwọ́, mo fi ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn sí ọ ní ọrùn, 12 mo sì tún fi òrùka sí ọ ní imú, mo fi yẹtí sí ọ ní etí, mo sì fi adé tó rẹwà dé ọ ní orí. 13 Báyìí ni mo ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú wúrà àti fàdákà; tí aṣọ rẹ jẹ́ funfun gbòò, aṣọ olówó iyebíye àti aṣọ tí a ṣiṣẹ́ ọnà sí. Ìyẹ̀fun kíkúnná, oyin àti òróró ni oúnjẹ rẹ. Ó di arẹwà títí ó fi dé ipò ayaba. 14 Òkìkí rẹ sì kàn káàkiri orílẹ̀-èdè nítorí ẹwà rẹ, nítorí dídán tí mo fi ṣe ẹwà rẹ ní àṣepé, ni
15 “ ‘Ṣùgbọ́n, ìwọ gbẹ́kẹ̀lé ẹwà rẹ, ìwọ sì di alágbèrè nítorí òkìkí rẹ. Ìwọ sì fọ́n ojúrere rẹ káàkiri sí orí ẹni yówù tó ń kọjá lọ, ẹwà rẹ sì di tìrẹ. 16 Ìwọ mú lára àwọn aṣọ rẹ, láti rán aṣọ aláràbarà fún ibi gíga òrìṣà tí ìwọ ti ń ṣe àgbèrè. Èyí kò yẹ kí ó rí bẹ́ẹ̀, tàbí kó tilẹ̀ ṣẹlẹ̀ rárá. 17 Ìwọ tún mú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ dáradára tí mo fi wúrà àti fàdákà ṣe fún ọ láti fi yá ère ọkùnrin tí ó ń bá ọ ṣe àgbèrè papọ̀. 18 Ìwọ sì wọ aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́ rẹ fún wọn, o sì tún gbé òróró àti tùràrí mi sílẹ̀ níwájú wọn. 19 Ìwọ tún gbé oúnjẹ tí mo fún ọ—ìyẹ̀fun dáradára, òróró àti oyin—fún wọn gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun olóòórùn dídùn; ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyìí, ni
20 “ ‘Àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin tí o bí fún mi lo ti fi rú ẹbọ bí oúnjẹ fún àwọn òrìṣà. Ṣé ìwà àgbèrè rẹ kò ha tó bí? 21 Tí ìwọ ti pa àwọn ọmọ mí, ìwọ sì fà wọ́n fún ère gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun. 22 Nínú gbogbo iṣẹ́ ìríra àti ìwà àgbèrè rẹ, ìwọ kò rántí ìgbà èwe rẹ, nígbà tí ìwọ wà ní ìhòhò, tó ń jàgùdù nínú ẹ̀jẹ̀.’
23 “Báyìí ni
30 “
32 “ ‘Ìwọ alágbèrè aya! Ìwọ fẹ́ràn ọkùnrin àjèjì ju ọkọ rẹ lọ! 33 Àwọn ọkùnrin máa ń sanwó fún àwọn panṣágà ni ṣùgbọ́n ìwọ lo tún ń sanwó fun wọn, tí ó tún ń fún àwọn olólùfẹ́ rẹ lẹ́bùn àti owó ẹ̀yìn kí wọn bá à le máa wá ọ wá láti gbogbo agbègbè fún àgbèrè ṣíṣe. 34 Nínú àgbèrè rẹ ìwọ yàtọ̀ sí àwọn alágbèrè obìnrin yòókù; nínú àgbèrè rẹ tí ẹnìkan kò tẹ̀lé ọ láti ṣe àgbèrè; àti ní ti pé ìwọ ń tọrẹ tí a kò sì tọrẹ fún ọ, nítorí náà ìwọ yàtọ̀.
35 “ ‘Nítorí náà, ìwọ alágbèrè, gbọ́ ọ̀rọ̀
43 “ ‘Nítorí pé ìwọ kò rántí ọjọ́ èwe rẹ ṣùgbọ́n ìwọ ń rí mi fín pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ó dájú pé, Èmi yóò mú gbogbo ohun tí ìwọ ti ṣe wa sí orí rẹ, ni
44 “ ‘Gbogbo àwọn to ń pòwe, ni yóò máa pòwe yìí mọ́ ọ pé: “Bí ìyá ṣe rí, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ rẹ̀ obìnrin.” 45 Ìwọ ni ọmọ ìyá rẹ ti ó kọ ọkọ rẹ̀, àti àwọn ọmọ rẹ̀; ìwọ ni arábìnrin àwọn arábìnrin rẹ tí ó kọ àwọn ọkọ wọn àti àwọn ọmọ wọn: ara Hiti ni ìyá rẹ, ara Amori sì ni baba rẹ. 46 Ẹ̀gbọ́n rẹ obìnrin ni Samaria, òun àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ n gbé ni apá àríwá rẹ, àti àbúrò rẹ obìnrin ní ń gbé ọwọ́ òsì rẹ̀, àti àbúrò rẹ obìnrin ti ń gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni Sodomu àti àwọn ọmọ rẹ obìnrin. 47 Kì í sẹ pé ìwọ rìn ni ọ̀nà wọn nìkan, tàbí ṣe àfiwé ìwà ìríra wọn ṣùgbọ́n ní àárín àkókò kúkúrú díẹ̀, ìwọ bàjẹ́ jù wọ́n lọ 48
49 “ ‘Wò ó, ẹ̀ṣẹ̀ tí Sodomu ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin ṣẹ̀ nìyìí. Òun àti àwọn ọmọbìnrin rẹ gbéraga, wọ́n jẹ́ alájẹjù àti aláìbìkítà; wọn kò ran tálákà àti aláìní lọ́wọ́. 50 Nítorí náà, mo mu wọn kúrò níwájú mi lójú mi gẹ́gẹ́ bi ìwọ ti rò ó, nítorí ìgbéraga àti àwọn ohun ìríra tí wọ́n ṣe. 51 Samaria kò ṣe ìdajì ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Ìwọ ṣe àwọn ohun ìríra ju tirẹ̀ lọ, ìwọ sì jẹ kí àwọn arábìnrin rẹ dàbí olódodo pẹ̀lú gbogbo ìwọ̀nyí tí ìwọ ti ṣe. 52 Gba ìtìjú rẹ, nítorí ìwọ ti jẹ́ kí arábìnrin rẹ gba ìdáláre. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ti burú ju tí wọn lọ, wọn dàbí olódodo ju ìwọ lọ. Nítorí náà rú ìtìjú rẹ, kí o sì gba ẹ̀gàn rẹ pẹ̀lú nítorí ìwọ ti jẹ́ kí àwọn arábìnrin rẹ dàbí olódodo.
53 “ ‘Bi o tilẹ̀ jẹ pe èmi yóò mú ìgbèkùn wọn padà, ìgbèkùn Sodomu àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin, pẹ̀lú Samaria àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin, nígbà náà ni èmi yóò tún mú ìgbèkùn àwọn òǹdè rẹ wá láàrín wọn, 54 kí ó bá à le rú ìtìjú rẹ, àti ẹ̀gàn gbogbo ohun tí ìwọ ṣe láti tù wọ́n nínú. 55 Nígbà tí àwọn arábìnrin rẹ, Sodomu àti àwọn ọmọbìnrin rẹ; Samaria àti àwọn ọmọbìnrin rẹ ba padà si ipò tí wọn wà tẹ́lẹ̀, ìgbà náà ni ìwọ náà yóò padà sí ipò àtijọ́ rẹ. 56 Ìwọ ko tilẹ̀ ní dárúkọ arábìnrin rẹ Sodomu ni ọjọ́ ìgbéraga rẹ, 57 kó tó di pé àṣírí ìwà búburú rẹ tú síta, báyìí ìwọ di ẹni ẹ̀gàn lọ́dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Edomu, Siria àti gbogbo agbègbè rẹ, àti lọ́dọ̀ àwọn ọmọbìnrin Filistini àti lọ́dọ̀ àwọn tó yí ọ ká, tiwọn si ń kẹ́gàn rẹ. 58 Èmi yóò gba ẹ̀san ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti àwọn iṣẹ́ ìríra rẹ ní
59 “Báyìí ni
16:3 El 16.45.