11
Àkàrà lórí omi 
 1 Fún àkàrà rẹ sórí omi, 
nítorí lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ìwọ yóò rí i padà. 
 2 Fi ìpín fún méje, àní fún mẹ́jọ pẹ̀lú, 
nítorí ìwọ kò mọ ohun ìparun tí ó le è wá sórí ilẹ̀. 
 3 Bí àwọsánmọ̀ bá kún fún omi, 
ayé ni wọ́n ń rọ òjò sí. 
Bí igi wó sí ìhà gúúsù tàbí sí ìhà àríwá, 
níbi tí ó wó sí náà, ni yóò dùbúlẹ̀ sí. 
 4 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo afẹ́fẹ́ kò ní fúnrúgbìn; 
ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo àwọsánmọ̀ kò ní kórè. 
 5 Gẹ́gẹ́ bí ìwọ kò ti ṣe mọ ojú ọ̀nà afẹ́fẹ́ 
tàbí mọ bí ọmọ tí ń dàgbà nínú ikùn ìyáarẹ̀, 
bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ kò le è ní òye iṣẹ́ Ọlọ́run 
ẹlẹ́dàá ohun gbogbo. 
 6 Fún irúgbìn rẹ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù, 
má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣọlẹ̀ ní àṣálẹ́, 
nítorí ìwọ kò mọ èyí tí yóò ṣe rere 
bóyá èyí tàbí ìyẹn 
tàbí àwọn méjèèjì ni yóò ṣe dáradára bákan náà. 
Rántí ẹlẹ́dàá rẹ ní ìgbà èwe rẹ 
 7 Ìmọ́lẹ̀ dùn; 
Ó sì dára fún ojú láti rí oòrùn. 
 8 Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn jẹ̀gbádùn gbogbo iye ọdún 
tí ó le è lò láyé 
ṣùgbọ́n jẹ́ kí ó rántí ọjọ́ òkùnkùn 
nítorí wọn ó pọ̀. 
Gbogbo ohun tí ó ń bọ̀ asán ni. 
 9 Jẹ́ kí inú rẹ dùn, ìwọ ọ̀dọ́mọdé ní ìgbà tí o wà ní èwe 
kí o sì jẹ́ kí ọkàn rẹ fún ọ ní ayọ̀ ní ìgbà èwe rẹ. 
Tẹ̀lé ọ̀nà ọkàn rẹ 
àti ohunkóhun tí ojú rẹ rí 
ṣùgbọ́n mọ̀ dájú pé nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni 
Ọlọ́run yóò mú ọ wá sí ìdájọ́. 
 10 Nítorí náà, mú ìjayà kúrò ní ọkàn rẹ 
kí o sì lé ìbànújẹ́ ara rẹ kúrò 
nítorí èwe àti kékeré kò ní ìtumọ̀. 
 Languages
Languages