1 Ní ọdún kẹrìndínlógójì ìjọba Asa, Baaṣa ọba Israẹli gòkè wá sí Juda ó sì kọlu Rama, láti ma bá a jẹ́ kí ẹnikẹ́ni lè jáde tàbí wọlé tọ Asa ọba Juda lọ.
2 Nígbà náà ni Asa mú wúrà àti fàdákà jáde nínú ilé ìṣúra ilé
4 Beni-Hadadi sì gbọ́ ti Asa ọba, ó sì rán àwọn olórí ogun rẹ̀ lọ sí àwọn ìlú Israẹli, wọ́n sì kọlu Ijoni, Dani, Abeli-Maimu, àti gbogbo ìlú ìṣúra Naftali. 5 Nígbà tí Baaṣa gbọ́ èyí, ó sì dá kíkọ́ Rama dúró, ó sì dá iṣẹ́ rẹ̀ dúró. 6 Nígbà náà ní ọba Asa kó gbogbo àwọn ènìyàn Juda jọ, wọ́n sì kó òkúta àti igi Rama lọ èyí ti Baaṣa ń fi kọ́lé; ó sì fi kọ́ Geba àti Mispa.
7 Ní àkókò náà wòlíì Hanani wá sí ọ̀dọ̀ Asa ọba Juda, ó sì wí fún un pé, “Nítorí tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé ọba Siria, ìwọ kò sì gbẹ́kẹ̀lé
10 Asa sì bínú pẹ̀lú sí wòlíì nítorí èyí, ó sì mú un bínú gidigidi tí ó sì fi mú un sínú túbú. Ní àkókò náà Asa sì ni díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn náà lára.
11 Àwọn iṣẹ́ ìjọba Asa, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni akọ sínú ìwé ọba Juda àti Israẹli. 12 [~1~]Ní ọdún kọkàndínlógójì ìjọba rẹ̀, Asa sì ṣe àìsàn pẹ̀lú ààrùn nínú ẹsẹ̀ rẹ̀. Bi ó tilẹ̀ jẹ pé ààrùn rẹ̀ lágbára, síbẹ̀ kódà nínú àìsàn rẹ̀ kò wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀
16:12 1Ọb 15.23,24.