1 [~1~]Ní ìgbà tí ó pe ọ̀rìnlénírinwó ọdún (480) lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ní ọdún kẹrin ìjọba Solomoni lórí Israẹli, ní oṣù Sifi, tí ń ṣe oṣù kejì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé
2 Ilé náà tí Solomoni ọba kọ́ fún
7 Ní kíkọ́ ilé náà, òkúta tí a ti gbẹ́ sílẹ̀ kí a tó mú un wá ibẹ̀ nìkan ni a lò, a kò sì gbúròó òòlù tàbí àáké tàbí ohun èlò irin kan nígbà tí a ń kọ́ ọ lọ́wọ́.
8 Ẹnu-ọ̀nà yàrá ìsàlẹ̀ sì wà ní ìhà gúúsù ilé náà; wọ́n sì fi àtẹ̀gùn tí ó lórí gòkè sínú yàrá àárín, àti láti yàrá àárín bọ́ sínú ẹ̀kẹta. 9 Bẹ́ẹ̀ ni ó kọ́ ilé náà, ó sì parí rẹ̀, ó sì bo ilé náà pẹ̀lú àwọn ìtí igi àti pákó kedari. 10 Ó sì kọ́ yàrá ẹ̀gbẹ́ sí gbogbo ilé náà. Gígùn ọ̀kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, ó sì so wọ́n mọ́ ilé náà pẹ̀lú ìtì igi kedari.
11 Ọ̀rọ̀
14 Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni kọ́ ilé náà, ó sì parí rẹ̀. 15 Ó sì fi pákó kedari tẹ́ ògiri ilé náà nínú, láti ilẹ̀ ilé náà dé àjà rẹ̀, ó fi igi bò wọ́n nínú, ó sì fi pákó firi tẹ́ ilẹ̀ ilé náà. 16 Ó pín ogún ìgbọ̀nwọ́ sí ẹ̀yìn ilé náà, láti ilẹ̀ dé àjà ilé ni ó fi pákó kedari kọ́, èyí ni ó kọ sínú, fún ibi tí a yà sí mímọ́ àní Ibi Mímọ́ Jùlọ. 17 Ní iwájú ilé náà, ogójì ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn rẹ̀ jẹ́. 18 Inú ilé náà sì jẹ́ kedari, wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà rẹ̀ pẹ̀lú ìrudí àti ìtànná. Gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ kedari; a kò sì rí òkúta kan níbẹ̀.
19 Ó sì múra ibi mímọ́ jùlọ sílẹ̀ nínú ilé náà láti gbé àpótí ẹ̀rí
23 Ní inú ibi mímọ́ jùlọ ni ó fi igi olifi ṣe kérúbù méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gíga. 24 Apá kérúbù kìn-ín-ní sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga, àti apá kérúbù kejì ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún; ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti ṣóńṣó apá kan dé ṣóńṣó apá kejì. 25 Ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá sì ni kérúbù kejì pẹ̀lú, nítorí kérúbù méjèèjì jọ ara wọn ní ìwọ̀n ní títóbi àti títẹ̀wọ̀n bákan náà. 26 Gíga kérúbù kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá. 27 Ó sì gbé àwọn kérúbù náà sínú ilé ti inú lọ́hùn ún, pẹ̀lú ìyẹ́ apá wọn ní nínà jáde. Ìyẹ́ apá kérúbù kan sì kan ògiri kan, nígbà tí ìyẹ́ apá èkejì sì kan ògiri kejì, ìyẹ́ apá wọn sì kan ara wọn láàrín yàrá náà. 28 Ó sì fi wúrà bo àwọn kérúbù náà.
29 Lára àwọn ògiri tí ó yí ilé náà ká, nínú àti lóde, ó sì ya àwòrán àwọn kérúbù sí i àti ti igi ọ̀pẹ, àti ti ìtànná ewéko. 30 Ó sì tún fi wúrà tẹ́ ilẹ̀ ilé náà nínú àti lóde.
31 Nítorí ojú ọ̀nà ibi mímọ́ jùlọ ni ó ṣe ìlẹ̀kùn igi olifi sí pẹ̀lú àtẹ́rígbà àti òpó ìhà jẹ́ ìdámárùn-ún ògiri. 32 Àti lára ìlẹ̀kùn igi olifi náà ni ó ya àwòrán àwọn kérúbù, igi ọ̀pẹ àti ti ìtànná ewéko sí, ó sì fi wúrà bò wọ́n, ó sì tan wúrà sí ara àwọn kérúbù àti sí ara igi ọ̀pẹ. 33 Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe òpó igi olifi onígun mẹ́rin fún ìlẹ̀kùn ilé náà. 34 Ó sì tún fi igi firi ṣe ìlẹ̀kùn méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ewé méjì tí ó yí sí ihò ìtẹ̀bọ̀. 35 Ó sì ya àwòrán kérúbù, àti ti igi ọ̀pẹ àti ti ìtànná ewéko sí ara wọn, ó sì fi wúrà bò ó, èyí tí ó tẹ́ sórí ibi tí ó gbẹ́.
36 Ó sì fi ẹsẹẹsẹ òkúta mẹ́ta gbígbẹ, àti ẹsẹ̀ kan ìtí kedari kọ́ àgbàlá ti inú lọ́hùn ún.
37 Ní ọdún kẹrin ni a fi ìpìlẹ̀ ilé
6:1 2Ki 3.1-13; Ap 7.47.